You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Dino Melaye: Ẹ seun tẹ́ẹ dójú tawọ̀n ẹlẹ́gàn
Sẹ́nétọ́ Dino Melaye tó ń ṣoju ẹkùn ìdìbò Ìwọ̀ Oòrùn Kogi, ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, ti gbóṣubà fún àwọn ará ìlu rẹ̀ lẹ́hìn tí ó jàwé olúborí nínú ìgbésẹ̀ láti yọ́ọ́ kuro nípò.
Ọ sọ lóri Twitter rẹ̀ ní Ọjọ́ Àìkú pé, òun kò ní dójú tì wón nítorí pé wọn ti fi àtìlẹ́hin wọn hàn fún òun.
Melaye, tó ṣì wà ní ilé ìwòsàn láti ọjọ́ tí àwọn ọlọ́pàá ti fẹ́ gbe lọ Kogí láti lọ jẹ́jọ́, ní "bí irọ́ lọ l'ógún ọdún, ọjọ́ kan lòtíto yóò ba. Òkùnkùn kò sì lè borí ìmọ́lẹ̀."
Ẹ ó rántí pé, àjọ elétò ìdìbò, INEC, ní nítorí pe idá márùń nínú ọgọ́rùń àwọn olùdìbò tó f'orúkọ sílẹ̀ ní agbègbè ìwọ̀ oòrùn Kogi, nìkan ló jáde láti wá ṣe àyẹwò orúkọ wọn ní ọjọ́ Àbámẹ́ta.
INEC sọ pe àwọn tí ó fọwọ́ sí ìwé láti yọ Dino Melaye dín diẹ̀ ní ẹgbẹ̀rú lọ́na igba (189,870), ṣùgbọ́n ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, àwọn tí wọ́n yẹ orúkọ wọn wò dín diẹ̀ ní ẹgbẹ̀rú mọ́kàndínlógún (18,742).