Èko: Ọ̀pá epo bẹntiróò gbina ní ìpájà, Èko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọ̀pá epo kan tí wọ́n fura pé àwọ́n ènìyàn kan ló se ìkọlù rẹ̀ ti gbiná ní agbègbè ìpájà ní ìlú Èkò. Ìròyìn tó kàn wá lára ni wípé ọ̀pá epo tó ti bẹ́ yìí gbiná ní agbègbè Peace Estate Baruwa, ìpájà nípinlẹ̀ Èkó.
Akitiyan ilé isẹ́ BBC látí sewadìí kíkún lọ́wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé isẹ́ àti àjọ tọ́rọ̀ kàn kó so èso rere sùgbọ́n agbẹnusọ fún àjọ tó ń rísí ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, NEMA sọ fún wa pe bẹ́ẹ̀ ló rí.
Àwọn olùgbé agbègbè náà sọ̀ wípé bẹ́ẹ̀ lórí.
Lọ́wọ́lọ́wọ́, wọn kò tíì sọ bóyá ẹnikẹ́ni fara gbá níbi ìsẹ̀lẹ̀ náà.
Ní ǹkan bí osù kan sẹ́yìn, a kó o jọ wípé irú ìsẹ̀lẹ̀ yìí kan náà wáyé ní agbègbè kan náà.








