Ile asofin fajuro si ọmọogun Cameroun to nwọ Naijiria laigbasẹ

Awọn asofin apapọ orilẹede Naijiria ti koro oju si bi awọn ọmọogun orilẹede Cameroun kan se tasẹ agẹrẹ wọ aala ilẹ Naijiria lawọn agbegbe kan.

Eyi lo si mu ki awọn asofin agba orilẹede Naijiria kesi minisita fun ọrọ aabo lati farahan niwaju igbimọ rẹ ko lee salaye lori isẹlẹ naa.

Lọjọ kẹẹdọgbọn osu kinni ọdun 2018 ni ọgọrin awọn ọmọogun orilẹede Cameroon tasẹ agẹrẹ wọ aala ilẹ Naijiria lẹkun Danare-Daddi/Danare-Bodom ni ibi ti wọn ti ji awọn eeyan marun gbe.

Igbesẹ yi si lawọn sẹnatọ ọhun ri gẹgẹbi iwa titapa si ofin orilẹede Naijira.

Bakanna lawọn asofin agba yi tun kesi ileesẹ ọmọogun Naijiria lati tubọ se alekun awọn ọmọogun ti yoo maa daabo bo aala ilẹ Naijiria ati awọn ẹnu ibode rẹ gbogbo.

ọkan-o-jọkan awọn asofin to sọrọ nibi ijoko ile lọjọru ni wọn koro oju si ohun to sẹlẹ yi.

Ninu ọrọ rẹ, Sẹnatọ Sam Egwu ni, o yẹ ki ile o bi minisita fun ọrọ abo nipa idi ti yoo fi la oju rẹ silẹ ti orilẹede miran yoo fi wọ orilẹede Naijiria, ti yoo si maa tẹẹ basubasu.

Ọrọ asepọ laarin orilẹede mejeeji yii ti n ni gbọnmisi-omi o too ninu lẹnu lọwọlọwọ yii, eyi ti ko si sẹyin wahala abẹle to n waye lorilẹede Cameroun nitori bi ẹkun guusu orilẹede naa se n beere fun ominira.

Isẹlẹ yi ti sọ eeyan bii ẹgbẹrun mẹwa ni guusu Cameroon di alarinkiri ati atipo lawọn ileto kaakiri ipinlẹ Cross rivers lorilẹede Naijiria.