South Africa: Awọn adoola ẹmi ti muse se ni ibudo iwakusa

Oríṣun àwòrán, AFP
Wọ́n ti n sisẹ́ lori ọ̀nà lati doola ẹ̀mí awọn tó tó eeyan marundinlọ́gọ́rùn tío há sínú ihó ilẹ́ níbìkan ti wọ́n ti n wa alumọ́ọ́nì goolu ni orílẹ̀èdè South Africa.
Agbẹnusọ kan fún ibùdó ìwakùsà ọun sọ pe iná ẹ̀lẹ́tiríikì ti pada sinu akasọ̀ èèbo tí yóò gbé àwọn awakùsà ọ̀ún padà sóké.
Ọjọ́rú to kọjá ni ìròyìn ti fi tó ni létí pe awọn ènìyàn wọ̀nyí há sínú ihò níbùdó ìwakùsà náà.
Ibùdó ìwakùsà Beatrix tó ọgọ́jọ máìlì sí ìlu Johannesburg, ti ihọ̀ tí wọn ti ń wa góòlù ọ̀ún si tó ẹgẹ̀rún mẹ́ta o lé lọ́gọ́jọ níwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà.
Iná mọ̀nàmọ́ná ló se mọ́namọ̀na
Ìròyìn fi tóni létí pé, iná ẹ̀lẹ́tíríìkì tó lọ lójijì lẹyin ti iji kọlu ọkan lara awọn oun èèlò amunawa ti ko jinna si ibudo iwakusa ọun ló fàá tí awọn awakusa naa fi há lojiji sinu iho ilẹ, ti wọn si ti n sa'pá lati ìgbà naa lati fa wọ́n jade.

Oríṣun àwòrán, Getty/AFP
Agbẹnusọ fún ibùdó ìwakùsà naa, James Wellsted sọ pe, ko si ẹ̀rí aridaju kankan pe ounkohun se ẹnikẹni ninu awọn awakusa naa, ati pe, wọn ti sagbékalẹ̀ ètò idanilẹ́kòó fun wọn ati awọn ẹbí onikaluku.
Awọn ẹgbẹ osisẹ sọ pe ẹru ba awọn pe ẹmi awọn awakusa to há sinu ihò ọun lee wa ninu ewu.








