You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Olùdámọ̀ràn Ambọ̀de, Gómìnà Ekó, Dèji Tinubu papòdà lórí pápá
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Oludamọran fun Gomina ipinle Eko lori ọrọ aje ati Idokowo, Ọgbeni Deji Tinubu ti doloogbe.
Deji to je Alaga tẹlẹri fun ajọ to n risi ọrọ ere idaraya nipinle Eko, di oloogbe nirọlẹ ana, nigba ti wọn n gba bọọlu ọlọresọre ni agbegbe Ẹpẹ nipinlẹ Eko.
Tinubu subu lori papa, ti ile-iwosan to wa ni Ẹpe si fidi ẹ mulẹ pe o ti dagbere faye.
Isẹlẹ yi wayẹ nibi ipagọ awọn alasẹ ijọba Gomina Akinwunmi Ambode lagbegbe Ẹpẹ.
Ọpọlọpọ eniyan lo nse idaro rẹ lori erọ ayelujara, Facebook ati Twitter, ti ọpọlọpọ si n sọ nipa igbe aye to gbe nigba to wa laye.