Ijọba fesi s'iwe aarẹ Ọbasanjọ

Ijọba apapọ orilẹ ede Naijiria ti da oloye Olusegun Ọbasanjọ lohun wipe airaye ko jẹ ki o mọ nipa isẹ ribiribi ijọba aarẹ Muhammadu Buhari n se.

Ijọba apapọ fẹsi si iwe ti aarẹ Olusegun Ọbasanjọ kọ si aare Muhammadu Buhari nibi ti o ti ni ko ma gbe apoti ibo lọdun 2019.

Nigba ti o'n ba awọn oniroyin sọrọ, Alhaji Lai Mohammed to jẹ Minisita fun ẹto iroyin ati aṣa sọ pe aba pẹ ki Muhammadu Buhari ma dije jẹ ọna ati se idiwọ fun isejọba.

Bakanna lo ni airaye Aarẹ Obasanjọ ko jẹ ki o le ri gbọgbọ akitiyan ijọba lati sọ eto ọrọ aje orilẹ-ede yi ji.

O dupẹ lọwọ aare Obasanjọ fun bi o ti se gbe osuba fun ijọba nibi ikoju iwa ibajẹ ati kikoju awọn to'n dun kukulaja mọni.

Alhaji Mohammed wi pe ijọba awọn ngbiyanju lati rii wipẹ eto ọrọ aje gunrege. Akawe orisirisi lo se to fi mọ bi ijọba ti se mu alekun ba owọ to wa ni asuwọn orilẹ-ede naijiria nilẹ okeere lati biliọnu mẹrinlelogun si ogoji biliọnu dọla.

Esi ọun tun se alaye bi iyipada ti se ba eto isẹ ọgbin, pipese oun eelo amuludun to fi mọ awọn nkan miran.

Lori ọrọ awon darandaran ti Obasanjọ mu ẹnu ba, Lai Mohammed ni ijọba ko jafara lati mu aawọ ọun wa si opin.

Esi to jẹ baban bari nibẹ ni eyi to nii se pẹlu ki Buhari ma se dije fun ipo aarẹ lọdun 2019 ti Obasanjọ gbaa ni iyanju.

Lai Mohammed kọ lati sọ boya Buhari yoo dije sugbọn o ni i '' lootọ ni awọn kan ti'n sọ wi pe ki Aarẹ Buhari dije nigbati awọn kan naa ni ko ma se dije. A ni igbagbọ wipe idiwọ ni eyi jẹ fun akitiyan ati koju gbogbo awọn ipẹnija to n kọju ijọba yi to sẹ wi pe a jogun wọn lati ọdọ awọn ijọba to saaju. Aarẹ Buhari ni ipinnu lati mu ileri ti o se fun awọn ọmọ orilẹede yi sẹ".