You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọlọpaa ti fi Oby Ezekwesili sile wọn si ti ni ko maa lọ sile
Awọn olopaa ti fi Oby Ezekwesili sile, o si ti kuro ni ahamọ wọn. Loni ni wakati diẹ seyin, ni awọn ọlọpaa mu arabinrin to jẹ oguna gbongbo lara awọn oludasile ẹgbẹ Bring Back Our Girls (BBOG) ati awon ọmọ ẹgbẹ ọun kan si ahamọ nilu Abuja.
Awọn eniyan ti bu ẹnu atẹ lu awọn ọlọpaa lori ọrọ yi, ti wọn si ni ki wọn fi Ezekwesili silẹ.
Ezekwesili lo fi ọrọ naa sọwọ lori oju opo Twita rẹ.
O se alaye pe isẹlẹ ọun ni se pẹlu bi awọn ti se'n beere fun itusilẹ awọn ọmọ ile ẹkọ Chibọk ti awọn Boko Haram jigbe.
Igbiyanju wa lati ba alukoro ọlọpa Abuja Jesse Manzah sọrọ jasi pabo. Ko da ipe wa pada, sugbọn ninu oun ti Ezekwesili fi sọwọ ninu ọrọ lori Twita, o fi han wipe ni ile isẹ ọlọpa ilu Abuja ni wọn ko wọn lọ.
Awọn ọmọ ẹgbẹ BBOG miran ti gba ori ẹrọ ayelujara Twita lati kede mimu ti ọlọpa mu wọn.
Eyi kii se igba akọkọ ti awọn ọmọ ẹgbẹ Bring Back Our Girls yoo ma ni ikọlu pẹlu ọlọpa.
A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin wa bi o ba se tẹwa lọwọ.