UNILAG TV: 'Isẹ yoo bẹrẹ laipẹ'

Oríṣun àwòrán, UNILAGTV/TWITTER
Oludari ile-ẹkọ giga ti Eko, Ọjọgbọn Oluwatoyin Ogundipe sọ pe Ile isẹ amohun-maworan ti ile-ẹkọ giga ti ilu Eko yoo bẹrẹ iṣẹ laipẹ.
Ọjọgbọn Ogundipe sọ fun BBC Yoruba wipe awọn alakoso ile-ẹkọ giga naa ti bẹrẹ isẹ ni pẹrẹwu lat se eto ti o tọ ti o si peye fun awọn akẹkọ ile ile giga naa.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo, o salaye wipe ile ẹkọ giga naa ti gbaradi lati wo ọrọ igbohunsafẹfẹ finni-finni lati ko awọn eniyan jankan-jankan ti wọn ni imọ nipa rẹ jọ fun isẹ ti o peye fun awọn akẹkọ.
Ẹ gbọ fọran naa nibi:









