Ronaldo ya ẹro ibanisọrọ dokita lati yẹ oju rẹ to bẹjẹ wo lori papa

Wọn gba Ronaldo nipa lẹgbẹ oju rẹ, o si bẹrẹ si ni sẹjẹ gan

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Wọn gba Ronaldo nipa lẹgbẹ oju rẹ, o si bẹrẹ si ni sẹjẹ gan

Ogbontarigi agbabọọlu ẹgbẹ Real Madrid, Cristiano Ronaldo ti ja abale airi ami ayo gba wọle rẹ lori papa nigba ti o se bẹbẹ lọjọ aiku. Sugbọn bi o ti se gba bọọlu wọ inu awọn kọ lo gba ori afẹfẹ.

Nigba ti wọn yọ jade nitori pe ofara pa, nise ni Ronaldo ya ẹrọ ibanisọrọ dokita rẹ lati fi yẹ oju rẹ wo ninu digi.

Isẹlẹ yi dẹrin pẹkẹ awọn to'n sọ bi ere idaraya naa ti se'n lọ ti ọrọ naa se wọn ni kayefi. Sugbọn nise ni Ronaldo nmi'ri rẹ.

Ninu ọrọ rẹ lẹyin idije naa, ile isẹ iroyin ere idaraya Reuters ni ''Ronaldo ti wa gbe afinju ara rẹ kọja ami''

Oju ẹrọ ere idaraya Benchwarmers se apejuwe rẹ gẹgẹ bi ''Isẹlẹ kayefi lati ọwọ Ronaldo to jọni loju julọ''

Bakanna lawọn ololufe ere bọọlu gba ori ẹrọ ayelujara twita lati fi iriwisi wọn sọwọ lori isẹlẹ naa.

Robbie Dunne sọ wipe"Wọn gba Ronaldo nipa lori, o si beere fun ẹrọ ibanisọrọ lati wo bi apa naa ti se to. Oun toju rẹ ri ko mu'nu rẹ dun rara''

Ogbontarigi agbabọọlu ẹgbẹ Real Madrid, Cristiano Ronaldo

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ogbontarigi agbabọọlu ẹgbẹ Real Madrid, Cristiano Ronaldo

O ti pẹ ti Ronaldo ti'n naani ẹwa ara r

Lootọ nipe awọn oniroyin ati ololufe ere idaraya dẹgun le Ronaldo pẹlu yiyẹ apa ara rẹ wo, sugbọn lotitọ, Ronaldo o sẹsẹ maa wu iru iwa bayi.

Lọdun 2011, Ronaldo ni awọn alatilẹhin ẹgbẹ alatako se abuku oun nitori pe oun jẹ agbaboolu to dun un wo loju, to si lowo lọwọ.

O ni ''awọn eniyan njowu mi ni'' ''ko ju bẹẹ lọ''

Isọwọ gba bọọlu Ronaldo lọjọ aiku se afihan rẹ gẹgẹ bi ogbontarigi agbabọọlu-emeji ọtọọtọ lo gba bọọlu wọnu awọn ki wọn to yọ jade lori papa.

Aseyọri ami ayo meje si ọkan ti Real Madrid se lọjọ aiku ti jẹ ki wọn gun oke si ipo kẹrin lori tabili La Liga.