Lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí wọ́n sin òkú n'Ibadan, àwọn afurasí olóogùn owó gé orí rẹ̀ lọ

Laarọ ọjọ Ẹti, lawọn afurasi ologun owo kan wu oku baba kan, ti wọn si bẹ ori oku naa lọ lagbegbe, Adegboro to wa ni Idi Arere, niluu ibadan.

Fidio kan to bọ si ori ayelujara lo ṣafihan pe orí pẹlu awọn eeya ara miran bíi irun ori baba agba naa ni awọn afurasi ologun owo naa mu lọ.

Oloogbe ọhun, to jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgọrin ki ọlọjọ to de ni ọmọ rẹ ni o jẹ ọlọpaa to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ.

Ọmọ oloogbe naa fi kun pe o jade laye lẹyin to ṣe agbako iku lẹyin iṣẹlẹ ijamba pẹlu kẹkẹ maruwa rẹ to fi n ṣiṣẹ.

Wọn ge ori, apa ati ifun oloogbe lọ

Ọkan lara awọn aburo baba naa ni iyalẹnu lọ jẹ fun awọn mọlẹbi ati oun paapa nigba ti wọn ranṣẹ pe awọn pe baba ti awọn sin, wọn ti ge ori ati àwọn ẹya rẹ miran lọ.

Lara awọn eekan ilu to ṣabẹwo si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ni Sheikh Taofeek Akeugbagold.

Akeugbagold fi ọkan awọn mọlẹbi oloogbe naa balẹ pe ọwọ awọn olopaa ipinlẹ Oyo yoo tẹ awọn to ìṣe ibi naa laipẹ.

O ni "A wa ni adugbo Idi Arere niluu Ibadan, nile Adegboro niluu Ibadan."

"Baba wa ti ẹ n wo ninu koto yii, wọn sin ni ana, nigba ti ilẹ yoo fi mọ lonii, wọn ti ge ori wọn, apa, wọn si ti yọ ifun rẹ lọ."

Akeugbagold sọ pe oun gbagbọ pe awọ eeyan to n gbe adugbo naa lo ṣiṣẹ laabi naa amọ ọwọ ọlọpaa yoo tẹ wọn laipẹ."

O ni "Nkan buruku ni eleyi ṣugbọn a mọ pe ọwọ Ọlọrun ati ọwọ awọn agbofinro yoo tẹ àwọn to ṣiṣẹ buruku naa."

Nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnbusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olawale Osifeso, lati sọ ohun ti oju ileeṣẹ naa to lori iṣẹlẹ ọhun ati ibi ti ohun ti wọn n ṣe nipa rẹ, agbẹnusọ naa ko fẹsi si ibere wa.