You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Tope Patricia Alabi: Àwọn ǹkan tó yẹ kí ẹ mọ̀ rèé nípa Tope Alabi
Gbajugbaja akọrin ẹmi ni awọn eniyan n sọrọ nipa ẹ lẹyin ti ileeṣẹ to n gbe awo orin rẹ jade gbe MTN, Airtel ati Glo lọ si ileẹjọ lori ẹsun pe wọn lu wọn ni jibiti.
Ohun to jẹ ki wọn gbe awọn ileeṣẹ ikansira-ẹni yii lọ sile ẹjọ ni orin 'Angẹli Mi' ti Tọpẹ Alabi gbe jade lọdun 2006.
Ẹsun ti wọn fi kan ileeṣẹ Airtel ati Glo ni pe wọn n ta orin Tope Alabi fun awọn onibara lori ikanni "caller tunes" lai gba aṣẹ lọwọ ileeṣẹ ọhun, ati pe lati ọdun 2011 ni awọn ileeṣẹ ikansira-ẹni mẹta yii ti n ta awọn orin naa.
- Nítorí orin 'Angeli mi' ti Tope Alabi kọ, iléeṣẹ́ MTN, Glo àti Airtel dèrò ilé ẹjọ́
- Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni mo ti ń bá Adẹ́rùpọkọ̀ ṣe eré tíátà - Tope Alabi
- Wo ohun tí Yinka Alaseyori sọ nipa Tope Alabi ní àyájọ̀ ọjọ́ ìbí rẹ̀
- Wòlíì Genesis fèsì lórí ọ̀rọ̀ Tope Alabi nípa orin 'Oniduromi'
- Ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ yóò wà ní Nàìjíríà, àtàwọn orílẹ̀èdè míràn wọ ọdún 2023 - IMF
- Wòlíì tó fí àbẹ́là gbígbóná jó ọmọ ọdún mẹ́tàlá lójú ara r'ẹ́wọ̀n
- Ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ló le yanjú ìṣòro ètò ààbò tó mẹ́hẹ - Obasanjo
Wọn ni orin mẹta ninu awo orin naa, 'Angẹli Mi', 'Ẹ Gbe Ga', ati 'Jesu Olurapada' ni wọn ta f'awọn onibara wọn lai gba aṣẹ lọwọ NPC Records.
Ta wa ni Tope Alabi ti wọn n sọrọ nipa rẹ?
- Gbajugbaja akọrin ẹmi ni Tọpẹ Alabi, ti wọn bi ni Ọjọ Kẹtadinlọgbọn, Osu Kẹwaa, ọdun 1970 ni ilu Eko amọ ilu Yewa, Imẹkọ ni ipinlẹ Ogun.
- Tope Alabi nikan ni ọmọbinrin ti awọn obi rẹ Joseph Akinyemi Abayomi ati Agnes Kehinde Obayomi bi laarin ọmọ mẹta
- Ileẹkọ Oba Akinyele Memorial High School, Ibadan ni Tope Alabi ti jade iwe mẹwa ni ọdun 1986
- Lati kekere lo ti darapọ mọ ere itage pẹlu Aderupọkọ ni ilu Ibadan nibi to ti bẹrẹ si ni kopa ninu ere apanilẹrin.
- Eyi jẹ ọna pato to gba pada bẹrẹ si ni ṣe iṣẹ akọrin to si n kọrin ẹmi lẹyin to fi aye rẹ fun Jesu Kristi.
- Soji Alabi to jẹ onimọ ẹrọ ni ọkọ Tope Alabi, ti wọn si ṣe igbeyawo ni ọdun 1998 lẹyin ti wọn pade ni ọdun 1994.
- Olorin Tope Alabi bi ọmọbinrin kan, Ayomikun ti oun naa jẹ olorin ati pe o maa n wa lara awọn elegbe iya rẹ.
Awọn iṣẹ ti Tọpẹ Alabi ti ṣe re e...
- Gbajugbaja akọrin naa kọkọ ṣiṣẹ ni ileeṣẹ amohunmaworan ti Naijiria, NTA ni ilu Ibadan nibi to ti ṣiṣẹ akọroyin fun ọdun kan ni ọdun 1990 si 1991.
- Bakan naa lo ṣiṣẹ ni ileeṣẹ Centre-spread Advertising Limited, Ilupeju , ni Eko ati Re-Union Nigeria Limited, Gbagada, ni Eko laarin ọdun 1991 - 1992.
- Ni ọdun 1994 ni Tope Alabi pada si ileeṣẹ tiata ti wọn pe orukọ rẹ ni "Alade Aromire Theatre Group" .
- Nibẹ lo ti n kọkọ kọrin si awọn tiata agbelewo Yoruba, ki o to bẹrẹ iṣẹ orin kikọ.
- Ọdun 2001 ni Tope alabi kọkọ gbe orin ore ti o common jade eleyii to jẹ orukọ ti awọn eniyan mọ ọ si to si sọ di ilumọọka.
- ti o si gbe awo orin miran jade ni ọdun 2003 to pe ni Iwe Eri ati Agbara re ni ni ọdun 2005.
- Titi di asiko yii, awo orin mọkanla lo ti gbe jade.
- Ni ọdun 2019 ni o ṣe awo orin the "spirit of light" to ni orin to lamilaaka "Lọgan ti o de" ninu rẹ, eleyii to se pẹlu gbajugbaja ayaworan Ty Bello.
O kere tan Tope Alabi ti kọ orin fun awọn fiimu agbelewo to fẹrẹ to irinwo ati eleyii to fun ara rẹ ṣe agbekalẹ orin naa.
Ami Ẹyẹ ti Tope Alabi ti gba
O gba ami ẹyẹ ''Gospel Artiste Of The Year'' ni ọdun 2015.
O gba ami ẹyẹ ''Proclamation Award at New York State Senate'' ni ọdun 2016.
Ni ọdun 2017 lo gba ami ẹyẹ ''Best Sound Track Artiste'' latọwọ ''City People's Movie''.
Bakan naa ni wọn fun un ni ami ẹyẹ Ọbabinrin to gbajumọ pẹlu ede Yoruba, ''Queen of the Yoruba language '' ni ọdun 2019.