Rotimi Salami on DNA: Dandan kọ́ ni kí o ṣe àyẹ̀wò DNA tí kò bá sí ẹni tó n bá ọ du ọmọ rẹ

Ẹnu ti n kun gbajugbja oṣere, Rotimi Salami lori ayelujara.

Eyi ko ṣẹyin ọrọ to kọ sori ayelujara Instagram rẹ pe ṣiṣe ayẹwo DNA ko sẹ pataki.

Lati asiko diẹ sẹyin ni awuyewuye ti n waye lori ayelujara ni Naijiria lori ọrọ ayẹwo DNA.

Awuyewuye naa bẹrẹ lẹyin ti iroyin jade pe gbajugbaja apanilẹrin, Nedu Wazobia, kọ lo ni akọbi ọmọ ti iyawo rẹ sọ pe oun bi fun un.

Ti aṣiri naa si tu lẹyin ti Nedu ṣe ayẹwo DNA fun ọmọ naa.

Bi awọn kan ṣe n faramọ ṣiṣe ayẹwo naa, ni awọn kan gbagbọ pe ọkunrin to bimọ, ko niyi bi ọkunrin to tọ ọmọ.

Ninu ero tiẹ to kọ, Rotimi Salami sọ pe ko yẹ ki ayẹwo DNA waye ayaafi ti "ẹnikẹni ba n ba ọ du ọmọ rẹ".

Salami sọ pe ko si eredi kankan ti ọkunrin gbọdọ fi lọ ṣe ayewo DNA fun awọn ọmọ to ba n tọọ, lati mọ boya oun ni baba wọn tabi bẹẹkọ.

O ni ẹni to tọmọ ni baba ọmọ, kii ṣe ẹni to ni àtọ to di ọmọ.

Ọrọ to sọ yii si ti mu ki ọpọ eeyan o ma bu ẹnu ẹtẹ lu u pe isọkusọ ni.

Awọn kan gbagbọ pe o ṣe koko ki ọkunrin mọ boya oun lo ni ọmọ tabi bẹẹkọ, ko to o pinnu pe oun yoo tọ ọ.