You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ondo Governorship Election: Díẹ ló kú kí wọn yọ Akeredolu ní ip`o Gomin`a, orí ló koyọ
Adajọ mẹrin ninu meje, lo fọwọ sii pe ki gomina Akeredolu wa nipo ti mẹta si sọ wi pe ko lẹtọ lati di ipo naa mu(4-3).
Agbẹjọro Agba, Festus Keyamo ti kesi ẹgbẹ oselu APC lati ṣọra lori idibo abẹle to yẹ ko wale ni opin ọṣẹ lati yan awọn adari ẹgbẹ ni wọọdu ati ni ipinlẹ kọọkan.
Eyi ko ṣeyin idajọ ileẹjọ to gaju lo lorileẹde Naijiria lori ẹjọ ti oldije lẹgbẹ oṣelu PDP fun ipo gomina nipinlẹ Ondo, Eyitayọ Jegede pe lati sọ wi pe Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ko laṣẹ lati di ipo gomina mu nitori alaga ẹgbẹ fidiẹ, Mala Buni jẹ gomina ipinlẹ Yobe.
Keyamo to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ati minisita fun ọrọ igbanisiṣẹ ninu atẹjade to fi ṣọwọ si ẹgbẹ APC, amọ ti awon oniroyin gbe jade ni Gomina Akeredolu ko ba kuna ni ileẹjọ kani Jegede pe ẹjọ mọ Gomina Buni lasiko to lọ si ileẹjọ kotẹmilọrun.
''Kekere bayii loku ki Akeredolu sọ ipo rẹ nu ni idajọ ileẹjọ to gajulọ nitori ko ba ofin mu ki ẹnikẹni ti wọn di ibo yan si ipo lorilẹede Naijiria ṣi ma a ṣe iṣe miran tabi di ipo mu, eleyii ti o mu ki Gomina Buni tapa si ofin pẹlu bo ṣe di ipo gomina ati alaga ẹgbẹ oṣelu APC mu.''
- 'Lábẹ́ òfin àjọ ECOWAS, kó ṣééṣe kí Benin Republic jọ́wọ́ Sunday Igboho fún Nàìjíríà'
- A ó bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ẹsun ti US fi kan Abba Kyari, Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ti pàṣẹ
- Èyí ni bí wọ́n ṣe pa akẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan tí wọ́n sì sọ òkú rẹ̀ sí orí àkìtàn
- Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà dá Akeredolu láre lórí ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo
''Adajọ mẹrin ninu meje, lo fọwọ si pe ki gomina Akeredolu wa nipo ti mẹta si sọ wi pe ko lẹtọ lati di ipo naa mu''.
''Ileẹjọ giga ninu idajọ wọn sọ wi pe o lodi sofin bi Gomina Buni ṣe dari eto idibo si ipo gomina nipinlẹ Ondo, amọ nitori Jegede ko pe e ni ẹjọ ni Akeredolu ṣe bori ni ilẹejọ''
''O ni ipo Buni tapa si aṣe iwe ofin orilẹede Naijiria, ẹka 183 ti ọdun 1999 pe gomina to wa ni ipo ko gbogbo di ipo alaṣẹ miran mu lorilẹede Naijiria.''
'' Kani Jegede pe ẹjọ mọ Buni ninu ipẹjọ rẹ ni, Eyitayo Jegede ati ẹgbẹ oṣelu PDP iba gba ipo gomina mọ Akeredolu lọwọ nitori aibọwọ fun ofin ti Buni tapa si.''
''Nitori adajọ mẹrin ninu meje, lo fọwọ si pe ki gomina Akeredolu wa nipo ti mẹta si sọ wi pe ko lẹtọ lati di ipo naa mu nitori Gomina Yobe to di ipo alaga ẹgbẹ oṣelu APC mu.''
Nitori naa, Keyamo kesi ẹgbẹ lati tete pe ipade pajawiri ki ọrọ naa ma bẹyin yọ nitori idibo sipo aaṛ ati idibo gbogboogbo to nbọ ni ọdun 2023.
- Evangelist/Dókítà/Oníròyìn Kemi Olunloyo sọ nípa ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ láàrin òun, ESABO, Jide Kosoko àti Iyabo Ojo
- Oúnjẹ tí àwọn Onífá tí wọn ń gbé wá sílé wa ló mù mí fi ẹsìn Krìstẹnì sílẹ dí Ogbójú Babaláwo àti Ẹ̀lẹ́bọ – Oluwo Olakunle
- A ó bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ẹsun ti US fi kan Abba Kyari, Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ti pàṣẹ
- Èyí ni bí wọ́n ṣe pa akẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan tí wọ́n sì sọ òkú rẹ̀ sí orí àkìtàn
- Ẹbí gba ẹ̀mí ọmọdébìnrin kan nítorí ó wọ ṣokoto "jeans"
- Oúnjẹ tí àwọn Onífá tí wọn ń gbé wá sílé wa ló mù mí fi ẹsìn Krìstẹnì sílẹ dí Ogbójú Babaláwo àti Ẹ̀lẹ́bọ – Oluwo Olakunle
Minisita naa ni ti wọn ko ba ṣọra ṣe ki wọn tete yọ Buni kuro ni ipo naa, awọn ẹgbẹ alatako yoo lo lati fi dabaru eto idibo to n bọ lọdun 2023 ati wi pe Buni ko lẹtọ lati pe ipade gbogboogbo kankan.
Keyamo wa rọ ẹgbẹ oṣelu APC lati dawọ idibo abẹlẹ ti wọn fẹ ṣe kaakiri ipinlẹ lati yan awọn adari wọọdu ''congress'' ati awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa ni ipinlẹ duro nitori yoo lẹyin ti wọn ba tẹsiwaju.
Ọjọ Kọkanlelọgbọn, Osu Keje, ọdun 2021 lo yẹ ki idibo lati yan adari wọọdu ati ipinlẹ kaakiri orilẹede Naijiria yẹ ko wayẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC.
Amọ, iroyin ni ababọ idajọ ileẹjọ gigajulọ lorilẹede Naijiria ti mu ki awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC kaakiri Naijiria pe ipada pajawiri lati jiroro boya yoo waye tabi ki wọn sun si iwaju.