You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Haruna Maitala, Aṣòfin Naijiria ọ̀mọ̀ rẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ méjì pádánú ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀
Asofin to n soju ẹkun ariwa Jos/Bassa ni Ile Aṣojusofin Naijiria, Haruna Maitala ti padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọkọ.
Ijamba ọkọ naa waye ni opin ọsẹ lasiko to n rin irinajo lọ ni opopona ilu Abuja si ilu Jos.
Asofin naa ku pẹlu ọmọ rẹ ọkunrin ati awọn oṣiṣẹ rẹ meji lasiko ti wọn n lọ fun igbeyawo ọmọ rẹ ọkunrin ni ilu Jos.
- Mo ti padà sí ẹ̀sìn òwúrọ̀ mi o! Ẹ̀ gb'Ọ́lọ́hun tóbi - Yomi Fabiyi
- Genesis Global: Sáká lara Woli Israel Ogundipe dá, kìí ṣe àìlera ló mú kí wọn fi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n
- Ogún ódún ni mo wà nígbà tí mo kọ́kọ́ ṣe ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n ó túká - Don Jazzy
- Wo ohun mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Yinka Odunmakin, agbẹnusọ Afenifere tó dágbére fáyé
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ Asofin naa, Josẹph Adudu fi sita ni ijamba ọkọ gbigbona naa lo mu ẹmi aṣofin Haruna Maitala lọ.
Bakan naa lo fi kun un wipe opin ọṣẹ naa ni wọn sin in ni ọna ẹsin musulumi.
Lẹyin naa ni awọn olubaṣiṣẹ rẹ ati awọn akẹgbẹ rẹ ti n ṣedaro rẹ.
Wọn ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi akinkanju eniyan, to fẹran araalu to si gbe igbeaye irẹlẹ lasiko to wa ni okeepe.
- Kí ló fa ìjà rọ̀fọ̀rọ́fọ̀ láàrin Toyin Abraham àti olólùfẹ́ rẹ̀ lórí ayélujára?
- Irọ́ ni o, kìí ṣe Boko Haram ló já ọkọ̀ òfúrufú ọmọgun Alpha Jet bọ́ - NAF
- Mo kọ láti gba lẹtà ọgá ọlọpàá, kí wọn má fi bọǹbù pa mí bíi Dele Giwa - Igboho
- Ọ̀daràn darandaran pàdà sí Igangan, wọ́n gé ọwọ ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́
- "Ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn, ẹ ṣe pẹ̀lẹ́, ilẹ̀ ń yọ̀"
Arakunrin Suleiman Yahaya-Kwande ti Haruna gba ipo lọwọ rẹ ni ile igbimọ aṣofin ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹni to ṣe mu yangan ni awujọ nitori bi o ṣe soju awọn eniyan rẹ ni ile aṣofin Naijiria.
Haruna ni ẹni kẹta to jẹ aṣofin ti yoo papoda ni ọdun 2021,ti aṣofin to n soju ipinlẹ Jigawa, Yuguda Killa naa jade laye ni nkan bi osu kan ṣẹyin ati Asofin Ossy Prestige.
Awọn asofin miran ti wọn ti se alaisi lati igba ti wọn ti bura wọle fun wọn ni ọdun 2019 ni Jaafaru Illiyasu, Mohammed Faggen-Gawo ati Rose Oko.