Asari Dokubo: Ọba Adetokunbo Tejuosho ní ààbò tó mẹ́hẹ ló jẹ́ kí ẹ̀yà kan fẹ́ fi Naijiria sílẹ̀

Ori Ade kan nilẹ Yoruba ti sọ pe eto abo to mẹhẹ lo jẹ ki awọn ẹya kan maa gbiyanju lati yapa kuro ni Naijiria.

Ọba Orile Kemta, Ọba Adetokunbo Tejuosho lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

Ọba Tejuosho ni ọrọ eto abo yẹ ko jẹ gbogbo eeyan logun nitori ti ko ba si eto abo to peye, ohun gbogbo yoo dẹnu kọlẹ ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ijọba le maa tiraka lori eto abo lootọ ṣugbọn awọn eeyan ilu ko ri akitiyan kankan ti wọn ṣe.

O ni "mo ti sọ ṣaaju pe awọn agbagba ilẹ Yoruba yẹ ko sọrọ lori eto abo to mẹhẹ, ki ilọsiwaju le waye nilẹ Yoruba ati ni Naijiria lapapọ."

Kabiyesi naa fi kun pe, o yẹ ki ijọba wa ọna abayọ si ọrọ abo to mẹhẹ naa, paapaa bi ijinigbe ṣe di tọrọ fọnkale kaakiri ni Naijiria.

Ori ade naa fi kun pe, awọn agbagba ilẹ Yoruba kan n gbabọde fun ilẹ Yoruba nitori ohun ti wọn yoo jẹ.

Lẹyin naa lo sọ pe ọna abayọ kan si ọrọ naa ni pe ki ijọba pe apero laarin awọn ẹya to wa ni Naijiria fun ijiroro lori bi Naijiria ṣe maa tẹsiwaju tabi ki onikaluku maa lọ ni ilọ tirẹ.

O ni oogun abẹnu gọngọ wa nilẹ Yoruba ti wọn le fi gba ara wọn silẹ lọwọ awọn ẹya kan to n dun mọhuru mọhuru mọ wọn, ṣugbọn okun kii ho ruru, ka wa ruru.

Agba Amofin Niyi Akintola ni iwa iditẹ si Naijiria ni Ikede Dokubo

Ẹwẹ, agbẹjọro agba kan, Adeniyi Akintola sọ pe ọrọ ti eekan ọmọ agbegbe Ijaw, Asari Dokubo sọ nipa eto abo Naijiria, ko ba ofin mu.

Ṣaaju ni Dokubo ti kọkọ kede ijọba Biafra lopin ọsẹ, to si ri ara rẹ gẹgẹ bii adari ẹya naa eyii to pe ni Biafra de Factor Customary Government.

Dokubo ni kaka ki kiniun Biafra maa ṣe akapo ẹkun ni Naijiria labẹ ijọba Fulani, koowa yoo ma se ọdẹ tiẹ ni ọtọọtọ ni, ti awọn yoo si ṣe ijọba ara awọn funra wọn.

Agbẹjọro agba naa sọ pe, ọna abayọ kan ṣoṣo si iṣoro Naijiria ni atunto bi nnkan ṣe n lọ, bi bẹẹ kọ, o ṣeeṣe ki ọrọ aabo ma ni ojutu fun ọjọ pipẹ.