Agbẹjọ́rò sọ̀rọ̀ lórí ìtumọ̀ nǹkan kò fararọ táwọn gomina kéde lórí ìfipá báni lòpọ̀

Yoruba ni onbọ onbọ awọn laa dẹ de e, amọ lode oni, oju ni wọn n mu to.

Idi ree ti igbimọ awọn gomina ipinlẹ ni Naijiria fi dide lati kede pe nnkan ko fararọ, nitori ọwọja iwa fifi ipa bawọn obinrin lopọ ati hihu iwa ipa si awọn abo ati ọmọde to n gogo yika Naijiria.

Atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ awọn gomina ipinlẹ, Kayode Fayemi fisita lẹyin ipade wọn lo sisọ loju ọrọ yii.

Nigba to n salaye ohun ti ikede nnkan ko fararọ naa tumọ, Agbẹjọro kan to ba BBC Yoruba sọrọ, Toyin Taiwo Ojo salaye awọn ohun to lee sẹlẹ pẹlu ikede naa.

Ohun ti ikede nnkan ko fararọ yoo bi nidii iwa ifipa bani lopọ:

Awọn ile asofin ipinlẹ yoo ṣe ofin to gbopọn tako iwa ifipa bani lopọ

O ṣee ṣe ki ijiya to le gidi bii ẹwọn gbere ati iku fidi mulẹ lori iwa ifipa bani lopọ

Ijọba yoo bẹrẹ si gbe owona kalẹ fun amulo Ileesẹ to wa fun ọrọ awọn obinrin ati awọn ọlọpaa, ki wọn le gbogun ti iwa aidaa naa

Asiko to ti ijọba yoo pese awọn irinsẹ ati imọ ẹ̀rọ igbalode lati gbogun ti iwa kotọ naa

Onimọ nipa ofin naa wa daba pe ijiya to yẹ ko kere julọ ta le fun ẹni to ba fipa bani lopọ ni ẹwọn gbere, pẹlu afikun wọn wọn tun lee ṣe idajọ iku fun onitọun.

O wa gba awọn obìnrin ti wọn ba fi ipa ba lopọ nimọran lati tete fi iṣẹlẹ naa to awọn Ọlọpa ati awọn Ileesẹ ìjọba pẹlu ẹgbẹ to n ja fun ẹtọ awọn obinrin leti, ki wọn lee tete dide si ọrọ naa.