Social Media Week 2020: Iléeṣẹ́ BBC yóò máa ṣíi yín lójú nípa ohùn obìnrin tó ń jó lọlẹ lórí ayélujára

Ọpọlọpọ lo gbagbọ pe bi wọn ba n kọ tabi sọ itan oju ti wọn maa fi n wo awọn odinrin ni ipo keji lawujọ. Ṣe ko wa yẹ ki ohun obinrin naa maa ja'ke ni ibẹrẹ pẹpẹ eto nkan ni?
Ọsẹ ayelujara ni ipinlẹ Eko n waye laarin ọjọ kẹtalelogun oṣu keji o si ti ni ọpọlọpọ eto alakalẹ ti wọn ni fun un yin lati lee mu aye ode oni tii ṣe ti awọn ọdọ dara sii.
Lọdun yii ninu eto naa, abala meji ni ileeṣẹ BBC yoo dari eyi ti wọn pe ni "Gbigbe ohun obinrin s'oke" eyi ti yoo waye lọjọ ẹti ọj kejidinlọgbọn. Akori abala keji ti waye lọjọ aje ọjọ kẹtalelogun oṣu keji.

Abala to ni ṣe pẹlu obinrin yii yoo da lori akanṣe iṣẹ kan ti ileeṣẹ BBc pe ni 50/50 eyi to n gba ọpọ obinrin niyanju lati maa kopa ninu awọn eto jakejado BBC.
Awọn olujiroro yoo fọrọwerọ lori oriṣiriṣi ọna ti ṣiṣe iroyin lee jẹ ki obinrin atawọn ọdọ pọ si i lati fun wọn ni ohun to ja oke lori awọn iroyin to wu wọn lati ka ati lati pin.
Awọn oṣiṣẹ BBC to wa lara awọn olujiroro yoo ṣafihan bi wọn ṣe ti mu eleyii wa si imuṣẹ kaakiri ilẹ Afirika lori ẹrọ mohunmaworan wọn, ẹr rẹdio ati lori awọn itakun ayelujara.
- Ọmọ mi ti ṣèlérí pé oun máa mú mi lọ sí òkè òkun k'àwọn SARS tó pá á - Iya Kazeem Tiamiyu
- Súnkẹ́rẹ fakẹrẹ ọkọ òpópónà marosẹ̀ Lagos-Ibadan tòní tún kọ sísọ
- Ọ̀jọ́ eérú t'ọdún yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀
- Ọmọ oyè wọ gbaga ọlọ́pàá nípìínlẹ̀ Ogun lóríi ayédèrú sabuké WAEC
- Ilé ẹjọ́ gíga jùlọ dúró gbọingbọin lórí ìdájọ́ lórí ìdìbò gómìnà Bayelsa

Abala ti BBC yoo ti sọrọ yoo yananan bi ẹ ṣe le fi obinrin sinu iroyin yin ati ọna ati bọ sori ayelujara ggẹ bi o ṣe ti n gbilẹ kan lasiko yii.
Itakun ayelujara ti di ohun kan ti ọpọlọpọ n lo koda ti awọn kan ti sọ ọ di iṣẹ ti wọn n ṣẹ
Ọsẹ itakun ayelujara (Social Media Week) ti di ọkan lara ipade apero nla eyi ti orilẹede mejila kaakiri agbaye maa n ṣe.













