You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kano: Àhesọ̀ ọ̀rọ̀ kan ní ọmọ náà ní àrùn ọpọlọ ni
Yoruba ni ọjọ gbogbo ni ti ole, ọjọ kansoso pere ni ti olohun.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu baba kan, to de ọmọ rẹ, Ibrahim Lawal, mọlẹ sinu ile rẹ fun odidi ọdun mẹẹdogun gbako.
Alabagbele ọmọkunrin naa ni agbegbe Shekar Dan Fulani, nijọba ibilẹ Kumbotso nilu Kano salaye pe, iya ọmọ naa ko gbe pẹlu wọn ninu ile.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣé ojúlówó ìwé ìdánwò ìṣìro WAEC tí yóò wáyé lónìí ló lu ayélujára pa bí?
- "Àwa Emèrè Onítẹ̀síwájú la ṣèpàdé nílé Elebuibon, kìí ṣe Oṣó àti Àjẹ́"
- Nǹkan wọ̀lú! Afurasí ikú ọ̀wọọ̀wọ́ l'Akinyele jápa mọ́ ọlọ́pàá lọ́wọ́
- Wo ọmọ Nàíjíríà tí wọn fi pósí ‘₦34m’ sin
- Yéèpà, òfin ìtakété síra ẹni forí ṣánpọ́n lásìkò ọdún Osun Osogbo
- Ẹ fura, iyọ̀ onímájèlé tó dóde ti gbẹ̀mí èèyàn méje!
- Ìtàn ayé Alájọ Ṣómólú rèé, tó ta mọ́tò ra kẹ̀kẹ́?
Dan Fulani ni gbogbo aayan awọn aladugbo naa lati ẹyin wa, lati doola ẹmi ọmọkunrin naa, lo n ja si pabo.
O ni lasiko ti awọn ọlọpaa n doola ọmọ naa, wọn ba ninu yara kan ti ilera rẹ ko si peye, ti wọn si da ounjẹ sinu abọ nla kan fun lati jẹ bii ẹranko.
Ibrahim Lawal yii si ni ọmọkunrin keji ti yoo wa ni iru ipo to buru jai bayii, ti ileesẹ ọlọpaa yoo doola ẹmi rẹ laarin ọjọ meji.
Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kano, Abdullahi Kiyawa salaye pe o ti to ọdun mẹẹdogun ti wọn ti so Ibrahim Lawal naa mọlẹ bii ẹranko, ninu ahamọ kan.
Kiyawa ni awọn ti gbe ọmọkunrin naa lọ sile iwosan fun itọju to peye, ti iwadii lẹkunrẹrẹ si n lọ lọwọ lori isẹlẹ naa.
Fidio kan to si n ja ranin-ranin lori ayelujara lo n se afihan ọkunrin kan ti wọn n wọ jade lati inu ile kan, to si n kerora gidi.
Kiyawa ni agbegbe Sheka Unguwar nijọba ibilẹ Kumbotso nilu Kano ni wọn ti doola ọkunrin naa.
Olori agbegbe naa, Mallam Bello Da'u Sheaka ni awọn mọ pe ọmọkunrin naa, bii baba rẹ, jẹ onimọ nipa ẹsin Islam.
Amọ o fikun pe ahesọ ọrọ kan lo n ja nilẹ pe Ibrahim Lawal naa ni arun ọpọlọ , tawọn ọrẹ rẹ si n saayan lati ba tọrọ owo, ki wọn le gbe lọ sile iwosan fun itọju.
Basaraken sisọ loju rẹ pe o ti to ọdun mẹjọ si mẹsan ti oun ti fi oju kan Ibrahim kẹyin, to si ni oun ro pe baba rẹ ti mu lọ sile ẹkọ ni.
Awọn ọlọpaa ko ba baba ọmọ naa nile lasiko ti wọn lọ doola ẹmi rẹ lọjọ Aiku
Ìjọba Kano fi páńpẹ́ òfin mú Ọba àwọn Oṣó lórí ẹ̀sùn jìbìtì
Ọga agba ajọ eleti gbaroye ati igbogun ti iwa ibajẹ ipinlẹ Kano, Muhiyi Magaji ti sọ fun BBC pe, idi ti ajọ ọhun ṣe n ti ilẹkun ṣọọbu awọn babalawo ati ariran ni ipinlẹ naa ni pe wọn n lu awọn eeyan ni jibiti.
Gẹgẹ bi ọrọ to sọ, wọn ti fi panpẹ ofin mu awọn ayederu babalawo mẹrin, wọn o si tẹsiwaju titi di igba ti awọn ara ilu yoo dekun ati maa fẹjọ wọn sun.
Magaji ṣalaye pe "A fofin mu okunrin kan ni ijọba ibilẹ Albasu to n pe ara rẹ ni Ọba awọn oṣo, to si jẹwọ fun wa pe ofege ni oun."
O ni ajọ naaa tun mu okunrin miran lagbegbe Makolo to pe ara rẹ ni alaga awọn babalawo ni gbogbo ipinlẹ Kano.
Olugbe ilu Kano kan, Sani Ibrahim sọ fun BBC pe oun ti ko sọwọ awọn gbajuẹ naa ri nigba ti oun n ṣe aisan.
Magaji sọ pe bi wọn ṣe n tu aṣiri awọn eeyan naa jẹ ara iṣe ajọ ọhun gẹgẹ bi eyii to n gbogunti iwa ibajẹ lawujọ
O ni oni jibiti ni awọn eeyan naa, wọn ko ni agbara kankan, ati pe ko yẹ ki awọn ara ilu maa bẹru wọn rara nitori o yẹ ki aye wọn dara ju bẹẹ lọ ka sọ pe lotọ ni wọn ni agbara.
Muhuyi kilọ fawọn eniyan pe ẹni to ba n wa ifa naa lo maa n ri ofo ati pe ẹni to ba n wa iwakuwa naa lo maa n ri irikuri.