You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ore-Lagos Accident: Ìjàmbá ọkọ́ gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀, èèyàn méje farapa
Awọn eeyan kan ti dero ọrun ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ loju ọna marosẹ Ọre si Eko, ni ijọba ibilẹ Odigbo, ti eeyan meje si farapa.
Ọkọ akero Toyota Hiace to ni nọmba AKL 930 YYY ati ọkọ ajagbe MAN, to ni nọmba FGB 737 XA ni wọn kọlu ara wọn.
Ẹni ti ọrọ naa ṣoju rẹ sọ fun awọn oniroyin pe "ijamba naa lo ṣẹlẹ loju ọna marosẹ Ọrẹ, ni agbegbe Adekunle, ọkọ ajagbe kan to n sare asapajude lo kọlu ọkọ akero to n bọ lati ọna Eko, eyi to yọri si iku awọn eeyan ti ọpọlọpọ si farapa."
- Èèyàn mẹ́ta kú nígbà tí ọkọ̀ bọ́ọ̀sì jábọ́ sí ódò Ọ̀ṣun
- Chelsea sáré kọjá kádàrá, góòlù kan ṣoṣo ní Vanlencia fi lù wọ́n
- Oògùn olóró cocaine ni Toyin Abraham fi ń sayé - Lizzy Anjorin
- Gómìnà ìpínlẹ Kwara yan Kọmíṣónnà tí ó kéré julọ!
- ‘A ó gbé ìdílé Kayọde Fayẹmi ṣépè tí àwọn akẹ́kọ́ tó ṣèṣe bá kú!’
- Mr Latin, Jide Kosọkọ àti Mama Rainbow sọ̀rọ̀ lórí ìjà Toyin ati Lizzy
Ijamba naa lo da sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ silẹ loju popo naa, ki ajọ awọn ẹṣọ oju popo, FRSC to wa ko awọn to gbẹmi mi, ati awọn to ṣeṣe nibi iṣẹlẹ naa lọ si ile iwosan.
Olori awọn oṣiṣẹ FRSC ni agbegbe naa, Olusegun Ogungbemide ni "Awọn mẹtala lo wa ninu ijamba naa ti awón kan si ti jẹ Ọlọrun nipe."
O salaye siwaju sii pe, ere asapajude lo fa ijamba ọhun.