You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọgá Ọlọ́pàá: Ẹ̀yin ọmọ Naijiria ẹ má bẹ̀rù, ọkọ̀ òfúrufú ọlọ́pàá yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní káàkiri ìpínlẹ̀
Ọga ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria, Mohammed Adamu ti sọ fun awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn ma foya.
O sọ eyi nitori ọkọ ofurufu awọn ọlọpaa yoo bẹrẹ si ni kaakiri awọn ipinlẹ lorilẹ-ede Naijiria.
Adamu ni idi ti awọn fi gbe igbeṣẹ yii ni lati koju iṣoro eto aabo to mẹhẹ kaakiri awọn ipinlẹ lorilẹ-ede Naijiria.
O fikun un pe ile iṣẹ awọn to wa ni Abuja ni yoo ṣiṣẹ naa fun opopona Abuja si Kaduna ati awọn agbegbe to wa ni Ariwa orilẹ-ede Naijiria.
Bakan naa ni Ọga ọlọpaa ni ileeṣẹ wọn tuntun to wa ni ipinlẹ Ondo ni yoo ṣiṣẹ ni agbegbe ipinlẹ naa ati awọn ipinlẹ to wa ni Iwọ-oorun orilẹ-ede Naijiria.
Amọ, atẹjade awọn ọlọpaa ko sọ bi ọkọ ofurufu yii yoo ṣe gbogun ti ijinigbe ni awọn agbegbe yii, tabi ọna ti awọn olopaa yoo gba lati ṣe iṣẹ wọn.
Bakan naa ni ko wọpọ ki awọn ọlọpaa ni ilẹ Afirika ma a lo ọkọ ofurufu lati gbogun ti ijinigbe ati awọn iwa ọdaran ni awujọ, amọ wọn ma n lo o ni igba kọọkan.