You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
N jẹ Arsenal ò ti dà òkùtà sí Newcastle nígbá báyìí?
Ẹgbẹ́ agbábọọ̀lù Arsenal náà ti darapọ̀ mọ Machestger City, Liverpool àti Tottenham nínú ìdíje Premiere League tuntun sáà yìí to ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀.
Arsenal náà jẹ́wọ́ ọmọ ọkọ bi wọn ṣe fi ojú Newcastle gbolẹ̀ nínú ìdíje àkọkọ ti wọ́n gba nínú òjò wẹ́liwẹ́li ní pápá St James lónìí
Bótilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo rẹ̀ fẹ́ lọ jáí níbẹ̀rẹ̀ nítori gbogbo àwọn ọmọ agbabọọlu tuntun ti wọ́n kowo rà ló wà lóri ìjọko Mesut Ozil àti Sead Kolasinac, Unai Emery gan o fara lálẹ̀ ní gbogbo sáà àkọ́kọ́.
Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yinbọ̀ Aubameyang ló gbá bọ́ọ̀lù sáwọn lẹ́yìn to gé Ainsley Maitland - Niles àti Martin Dubravka légèé tán.
Nicholas Pepe àti Dani Ceballos o wulẹ̀ le ta pútu bótilẹ̀ jẹ pé Emery fún wọ́n ni ààyé láti fí orúkọ wan hàn níle aláró.
Gbogbo ìgbìyànjú Newcastle láti gba ẹsan pàda, pabo ló jási oo
Gbogbo àwọn ọmọ ti ikọ agbábọọlu Arsenal rà ni Chelsea naa kan ludo lónìí lái foya rárá, Alexandre Lacasete àti David Luis, bákan náà ni Pepe ti wọ́n rà láti France náà o gbẹ́yìn ninu ìdíje tònìí
Ẹ̀wẹ̀, ẹnikan kò tẹ̀ fún ìkeji nínú ìfẹsẹwọnsẹ láàrin Leicester city àti Wolves.