World Happiness Day: Orílẹ̀èdè Austria ló gba ipò Australia nínú àwọn èèyàn tó láyọ̀ jùlọ

Ìdùnú jẹ́ ǹkan to ṣe pàtàkì nínú ìgbé àyé ọmọ ènìyàn, a lè fi ìdúnú wé ìmọ̀lára tí kò ṣe ṣe àkàweé sùgbọ́n tó ń dédé wá láti ìnú ènìyàn.

Awọn onimọ sàlàyé pé ó ṣe pàtàkì kí ìnú ènìyàn máà dún ni gbogbo ìgba, kí ẹmi baa lè gùn.

Gẹ́gẹ́ bí òní ṣe jẹ́ àyájọ ọjọ́ ìdùnnú lágbàyéé, à ń ṣe àgbẹyẹ̀wò àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́wàá ti wọn ní ìdùnù jùlọ lágbàyé lọdun 2019.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àlàyé àwọn orilẹ̀-èdè yìí wà nínú àtẹjade ti àjọ ìṣọ̀kan orilẹede àgbáye (UN) gbé jáde ní àyájọ ọjọ́ òní, ogunjọ oṣù kẹta ọdun 2019.

Finland: Ìgbà keji rèé léra wọn ti Finland yóò gba ipo kinni ninu awọn orilẹ̀-èdè to ní ìdùnú jùlọ, ìdí ni pé wọn ni ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tó ni ìmọ̀ àtinudá

Awọn orilẹ yoku to ri ipo mu ni Denmark, Norway, Iceland, Nertherland, Switzerland, Sweden, New Zealand, Canada, Austria

Ǹkan mẹ́fà ni wọn ṣe ìgbéléwọ̀n fún àwọn orilẹ̀-èdè yìí, tó fi mọ bí owo ṣe ń wọlé sí, òmìnira, ìgbẹ́kèlé, ẹmi gígùn àti aláfià, ìrànwọ́ fún ìgbé àyé amúlùdùn àtí bí àwọn ará ìlú ṣe ń fẹ́ràn àra wọn sí.

Ìwádìí fi hàn pé, gbogbo ànfàni yìí kìí ṣe fun àwọn onílùú nìkan, bí kò ṣe àwọn míràn ti wọn wá tẹ̀dó si orílẹ̀-èdè wọn náà.

Ní ọdun tọ kọja, àwọn ènìyàn Finland ní inú wọn dùn julọ ni gbogbo àgbáyé, bàká náà ni inú àwọn àtìpó ibẹ̀ ló dùn jùlọ.

Wọn máa ń san owó orí to ga gọbọi sùgbọ́n wọn ni ìgbágbọ́ nínú ìjọba wọn tó bẹ́ẹ̀, ti wọn fi n gbé ìgbé aye òmìnira, wọn ni ìfẹ́ ara wọn.

Díẹ̀ nínú ǹkan to yatọ ninu orílẹ̀ èdè mẹ́wàá ti inú wọn dùn jùlọ lọ́dún yìí, ni Austria tó gba ipò Australia