Linda Ikeji: Gbájugbaja àkọ̀ròyìn ẹ̀rọ alátagbà bímọ tuntun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajúgbajà akọròyìn, àkọ̀wé, to tun jẹ onísowò nígbà kan rí, Linda Ikeji ti bímọ ọkunrin làntì-lanti.

Línda rìnrìn àjò lọ sí ìlú òyìnbó láti lọ bí ọmọ náà tó sì kédé rẹ lóri àtẹ̀jíṣẹ́ instagram rẹ̀ lówùrọ̀ òní.

Linda kọ̀ láti jẹ̀ kí àwọn olólùfẹ́ rẹ mọ orúkọ ọmọ tuntun náà bó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní baby J láti osẹ̀ tó kọjá

Ikeji tó jẹ olówó jùlọ nínú àwọn àkọroyìn ori àtagbà tí ṣe ìkíni kààbọ fún ọmọ tuntun náà ní orílẹ-èdè Amẹrikà láti osẹ̀ tó kọjá nígbà ti wọn ń reti ọmọ jòjòló.

Psquare Peter Okoye, àbúro Linda, Laure Ikeji Kanu àti ọkọ rẹ̀ wà lára àwọn to wà níbi àpejẹ náà.