You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdájọ́ Sàràkí: Ẹnu kò sìn lára Sàràkí àti Buhari
Ilé ẹjọ́ gíga orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti fagilé gbogbo ẹsun tó níi ṣe àìkéde dúkìá ti ìjọba àpapọ̀ fi kan ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin agba, Bukola Saraki, to si rii bí èyí ti kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.
Ilé ẹjọ́ náà ni kò sí ẹ̀rí tó dáju lórí gbogbo ẹsun ti wọn kan-an
Adajọ Dattijo Muhammad tó darí ìgbimọ ẹlẹ́ni márùn-un to gbọ igbẹjọ náà nilé ẹjọ́ sọ pe gbogbo ẹri to wà níwajú ilé ẹjọ́ jẹ́ àhesọ lásán.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Àbájáde ìgbẹ́jọ́ ọ̀hún wáyé nitorí pé àwọn ẹlẹ́rìí mẹ́rin to yojú sí ilé ejọ́ tó ń rí sí ìkédé ohun ini ẹni (CCT) kò fi di ẹri wọn múlẹ̀ tó, lati ti ọwọ́ ààrẹ ilé ìgbìmọ asòfin bọ sọ̀lọ̀ ẹsun ti wọn fi kan-an.
Lọ́sàn-àn yìí ní adájọ́ Centus Nweze sọ pé Bukola Saraki jàre ẹsun náà, tó si da ẹsun ìjọba àpapọ̀ sí igbó.
Wayi o, awọn ọmọ Naijiria ti n fi ero wọn han lori idajọ ileẹjọ giga to fagilé gbogbo ẹsun tó nii ṣe pẹlu àìkéde dúkìá ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin agba, Bukola Saraki, ti ìjọba àpapọ̀ fi kan an.
Bukola Saraki, nigba to n fesi ninu atẹjade to fi sita sọ wi pe, igbẹjọ naa to ti bẹrẹ lati ọdun 2015, fihan gbangba pe, olotitọ eniyan ni oun, ati wi pe idukoko-mọni ni ẹsun ti wọn fi kan oun.
Kin ni awọn ọmọ Naijiria ri si idajọ ọhun ?
Lara awọn eniyan to fi ero wọn han loju opo kansiraẹni ‘Twitter’, fi ẹsun kan Aarẹ Buhari wi pe oun ati awọn osisẹ rẹ ni wọn wa ni idi ẹsun ti wọn fi kan aarẹ ile igbimọ asofin agba naa.
Wọn fi kun pe ijọba yoo tun pariwo pe ẹka idajọ ni orilẹede Naijria ko se isẹ wọn bii isẹ.
Amọ, awọn ẹlomiran lori Facebook ati Twitter fi ẹsun kan ileẹjọ wi pe otubantẹ ni igbẹjọ ti wọn se, ati wi pe iwa ibajẹ ti gbinlẹ lorilẹede Naijiria, paapaa ni ẹka eto idajọ.