Karin Berber tó jẹ Ọ̀jọ̀gbọn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì rọ ìran Yoruba láti mójú to àsà àti ìṣẹ̀ṣe

Àwọn ohun to wà nínú ewì Yoruba pọ̀ nínú ohun tó ń farahan nínú igbe aye ojojumọ ilè kárọ̀-oò-jíire

Ewi Yoruba maa n kilọ iwa ibajẹ, o maa n gbani nimọran, o maa n yonbo iwa rere, o tun maa n jẹ ki ori ẹni wu.

Asiko ti to ki awọn ọmọde mọ pataki ewi kike ati oriki ki ede Yoruba ma baa parun.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Barber Karin ti ilé ìwé Birmingham ló rọ ẹ̀yà Yoruba bẹ́ẹ̀ láti fóju àsà yanjú ìsoro tó ń ṣẹ̀lẹ̀ láwùjọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Óhún nínú ọ̀rọ̀ àpilẹkọ rẹ̀ níbí ayẹyẹ kan nílù Oshogbo.

Ó ní kí àwọn Yorùbá máà kó ẹyin àsà Yoruba sínú agbọ̀n kan, nítori fífi onírúurú ojú wo àsà Yoruba lọ̀nà àbáyọ.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Barber ní tí wọn ba fi ojú pàtakì àsà ilẹ̀ Afíríkà àti àwọn ìtan wọn sínu ìṣèṣe, yóò ràn wọn lọ́wọ́ láti rí ojúutu sí àwọn ńkan to ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn.

Bákan náà ọ̀nà àbáyọ yóò wà fún àwọn nkan tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò yìí àtí ìsòro àgbáye lọ́jọ́ iwájú.