Ẹ̀bùn Adégborúwà: Àwọn ọmọ-onílẹ̀ lo n fi tipa gba ilẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ènìyàn márùn-ún ló pàdé ólọ́jọ́ wọn, nígbà tí àwọn ọmọ onílẹ̀ àti ọlọ́pàá ya wọ agbègbe Makoko.

Ìròyìn to tẹ wá lọ́wọ́ so pé, àwọn ọmọ onílẹ̀ ló ń gbìyànjú láti gba ilé kan, táwọn onílé náà si kọ jalẹ̀ láti jọ̀wọ́ ilé náà fún wọn.Ṣùgbọ́n ṣàdédé ni àwọn ọmọ onílẹ̀ tún yọjú ni ọjọ ẹti, ni ifowosowopo pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá àti àwọn òsìsẹ ìgbìmò amuseya fún ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó, tí wọn sì dojú ìjà kọ àwọn ènìyàn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn ará Makoko so pé, ìyàlẹ́nu lọ je lati ri awon ọmọ onílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá, Ó ní, wọn kọ́kọ́ lọ ìjọ Àpọ́sítélì kan ládùúgbò òhún, tí wọn lọ bá nkan je nibẹ, leyin náà, ni wọn bere sini bá ilé jẹ aarin ládùúgbò, tí wọn sì ń pa ènìyàn lọ́sàn-án gangan.

Lásìkò to ń sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù táwọn ọmọ onílẹ̀ ohun ṣe, agbajero kan, tó tún jẹ́ ajá fẹ́tọ̀ọ́ ìlú, Ebun-Olú Adegboruwa ṣàlàyé pé, ó ṣe ni láàánú pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ wáyé.Ó wá bù ẹnu àte lu irú ìwà bẹ́ẹ̀ pé àwọn òsìsẹ ìjọba lọ́wọ́ sí gbigba ilẹ̀, ó ní ilé ẹjọ́ tí dájọ, to sì gbé fún àwọn ará ìlú náà.

Ó ní awuyewuye àdúgbò náà (orí òkè) bẹ̀rẹ̀ lodun díè sẹ́yìn, tí wọn sì jàre bò nílé ẹjọ́ lábẹ́ Gani Fawehinmi, ṣùgbọ́n síbè àwọn kan nínú ìjọba sì faake kori, láti gba ilé náà pẹ̀lú ipá.