You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo iléẹ̀kọ́ tó ń pèsè ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ aláìní, ṣùgbọ́n tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun ní àwọn kò tíi dá a mọ̀
Wo iléẹ̀kọ́ tó ń pèsè ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ aláìní, ṣùgbọ́n tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun ní àwọn kò tíi dá a mọ̀
Alufa Victor Ayọdele Bashọla ni oludasilẹ ile ẹkọ Kingston Montessori Schools.
O da ile ẹkọ naa silẹ lati jẹ anfani fun awọn ọmọ alaini ti awọn obi wọn ko lee ran nile ẹkọ.
Ni agbegbe Akute ni ile ẹkọ naa wa, lọdun 2021 ni Alufa naa si da a silẹ.
Alufa Bashọla ni imisi Ọlọrun ni oun gba to fun oun ni itni lati da ile ẹkọ naa silẹ gẹgẹ bi ara ọna lati pese ẹkọ ọfẹ fun awọn alaini lawujọ.
Gbogbo ohun ti awọn akẹkọọ to ba lanfani lati wọ ile ẹkọ naa nlo lo jẹ ọfẹ, lati ori ẹkọ ti wọn n kọ , aṣọ ileẹkọ, aga ati tabili , koda wọn n pese ounjẹ fun awọn akẹkọọ naa nibẹ.