You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mi ò mọ ohun tí mo ṣe tí ìjọba America fi gbẹ́sẹ̀ lé ìwé ìrìnnà mi- Ọ̀jọ́gbọ́n Wole Soyinka
Agba onkọwe nni, Ọjọgbọn Wole Soyinka, ti kede pe ijọba orilẹede America ti gbesẹ le iwe irinna oun si orilẹede naa, eyi ti a mọ si Visa.
Soyinka to ni oun ko le wọ America lasiko yii, kede ọrọ naa lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kẹwaa ọdun 2025 yii,nibi ipade oniroyin to waye niluu Eko.
Ọjọgbọn Soyinka sọ pe oun ko tiẹ mọ idi ti orilẹede America fi fofin de oun lati ma le wọ ilu naa. O loun ko ranti pe oun ṣe wọn lẹsẹ kankan.
"O yẹ ki n pe ipade yii kawọn eeyan to wa l'America ti wọn n reti mi fun eto kan tabi ikeji le mọ, ki wọn ma si ṣe fi akoko wọn ṣofo
"Mi o ni fisa, wọn ti fofin de mi, dajudaju, lati America ni. Bi ẹ ba fẹ ri mi, ẹ mọ ibi ti ẹ ti le ri mi.'
Bẹẹ ni Ọjọgbọn Wole Soyinka sọ fun awọn akọroyin.
Bo tilẹ jẹ pe Ọjọgbọn Soyinka funra rẹ ko mọ idi ti ai le wọ America naa fi kan an, ohun ti ọpọ eeyan n sọ ni pe yoo ni lati jẹ pe ijọba ilẹ naa ṣe n din awọn arinrinajo ku lo fa a.
Bakan naa ni ẹka iroyin kan sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe bi Soyinka ṣe ni oun ko ni ida ilẹ America loun nigba ti wọn ni ki awọn eeyan to n ni iru fisa rẹ wa fun ifọrọwerọ kan loṣu to kọja lo fa ohun to ṣẹlẹ yii.
''Wọ́n kọ lẹ́tà sí mi lọ́jọ́ kẹtalelogun oṣù Kẹwàá''
Gẹgẹ bi agba onkọwe yii ṣe tẹsiwaju ninu alaye rẹ, o ni ọfiisi to n ri si iwọle si America kọwe soun lọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹwaa yii.
Ninu iwe naa lo ni wọn ti ṣalaye pe ọga agba to n ri si wiwọle si America lati Eko, ti fofin de fisa rẹ, gẹgẹ bi aṣẹ ẹka to n paṣẹ iwọle si orilẹede naa.
Ẹka NIV ni Soyinka sọ pe o kọ lẹta naa.
Wole Soyinka ni oun ko huwa to tabuku ofin America ri, wọn ko dajọ foun nibẹ ri, oun ko si lu ofin wọn nibi kankan ri ki wọn too fofin de oun bayii.
Ẹya fisa B1/B2 ni Soyinka n lo, eyi to wa fun awọn arinrinajo to kan wọle fun igba diẹ ti wọn yoo si pada sibi ti wọn ti wa.
Ọjọgbọn Soyinka sọ pe oun ko tiẹ kọkọ ka lẹta naa kun nigba to de, o ni oun ro pe awọn onijibiti ni wọn n fi orukọ oun da ara to wu wọn ni.
Ṣugbọn nigba toun ri i pe America lo ti wa loootọ, ohun to ṣokunfa rẹ ko ye oun.