You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwòkọ́ṣe ni mo jẹ́ fún aráàlú, àwọn ohun àmúyangàn ni mo máa ń ṣe -Alaafin Oyo
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ọmọ onílùú kìí fẹ́ kó tú.
Aláàfin ìlú Oyo, Ọba Akeem Owoade I ti sọ pé bí ìlú Oyo yóò ṣe ní ìlọsíwájú ni gbogbo nǹkan tó wà lọ́kàn òun, tó sì ń ṣe atọ́nà gbogbo ìgbésẹ̀ tí òun ń gbé.
Ọba Owoade sọ fún BBC News Yoruba, lasiko ifọrọwerọ pẹlu rẹ, pé ṣáájú kí òun tó di Aláàfin ni òun ti máa ń gbé ìgbésẹ̀ láti ri pé àwọn amáyédẹrùn wọ ìlú Oyo.
Oríadé náà ní àwọn àǹfààní kan tí òun ní, gẹ́gẹ́ bí ọmọ orílẹ̀ èdè Canada, jẹ́ kí òun le máa wọ àwọn ibìkan.
O ni eyi tun jẹ kí òun sì ní àǹfààní láti máa bá àwọn iléeṣẹ́ kan sọ̀rọ̀ láti pèsè àwọn ohun tó le bí ìrọ̀rùn fáwọn èèyàn ìlú Oyo.
"Ìwà lẹ̀sìn, n kò bá ẹ̀sìn kankan ṣe ọ̀tá torí gbogbo ẹ̀sìn tó bá ti wa nílùú, ni ti ọba"
Ó ní èyí ló ṣokùnfà bí àwọn ṣe rí àwọn ohun èèlò ilé ìwòsàn kan gbà, léyìí tó jẹ́ ohun tí òun ti ń ṣe, kí wọ́n tó fi òun jẹ́ Aláàfin.
Nípa ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, Ọba Owoade ní òun kò bá ẹ̀sìn kankan ṣe ọ̀tá nítorí gbogbo ẹ̀sìn tó bá ti wa nílùú, ni ti ọba.
"Láti ìgbà tí mo ti dórí àlééfà, bí wọ́n ṣe ń ṣọdún Ṣàǹgó, lẹ̀ ń rí mi ní mọ́ṣáláṣí, la lọ ń kírun, báwọn oní ṣọ́ọ̀ṣì bá dẹ̀ pé náà, a máa yọjú síbẹ̀ ni, torí pé èmi mọ̀ pé ìwà lẹ̀sìn."
Aláàfin tún jẹ́ kọ di mímọ̀ pé gbogbo nǹkan tí òun bá fẹ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba ni òun máa ń làkàkà láti jẹ́ nǹkan àmúyangàn nítorí àwòkọ́ṣe tí òun jẹ́ fún aráàlú.
"Àwọn nǹkankan wa tó jẹ́ pé mo lè ṣe àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ọba mi ò le ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́."
Ọba Owoade fi kun pé òun kò ní èròńgbà láti kó ìyàwó jọ bíkòṣe pé bí ìlọsíwájú ṣe máa wáyé ní ìlú Oyo ló jẹ́ ohun tó jẹ òun lógún.