You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"Àwọn dókítà yọ kíndìnrín mi láì sọ fún mi, oṣù kẹta rèé tí mi ò lè tọ̀, ṣe ni inú mi ń wú tí mo bá jẹun kékeré"
Ọ̀gbẹ́ni Joshua Afolayan, ẹni tó ní àìsàn kíndìnrín, ló lọ sílé ìwòsàn olùkọ́ni ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ekiti State University Teaching Hospital, EKSUTH fún iṣẹ́ abẹ láti yọ kíndìnrín rẹ̀ kan tí kò dára náà nù.
Ṣùgbọ́n lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà ni Afolayan kò rí ìtọ̀ tọ̀, tó sì lọ ṣe àyẹ̀wò míì láti mọ ohun tó ṣokùnfà ìdí tí kò fi rí ìtọ̀ tọ̀ bó ṣe yẹ.
Afolayan ń fẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn EKSUTH pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ yọ kíndìnrín òun láì sí ìmọ̀sí òun níbẹ̀ èyí tó ń ṣe àkóbá fún ìlera òun.
Ó ni sọ pé láti ìgbà tí òun ti ṣe iṣẹ́ abẹ náà ni ara òun ti ń bó, ti ikùn òun sì máa ń wú nígbà tí òun ba jẹ oúnjẹ kékeré.
Nígbà tó ń ṣàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé, Afolayan sọ pé lẹ́yìn tí òun ṣe iṣẹ́ abẹ tán ni òun ri pé ọ̀pọ̀ àwọn dókítà pé òun lórí tí wọ́n sì ń kùn ṣùgbọ́n ohun tí wọ́n ń sọ kò yé òun.
"Àwọn dókítà sọ fún mi pé kíndìnrín tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa tẹ́lẹ̀ ń bá èyí tí wọ́n yọ kẹ́dùn, ni kò ṣe ì tíì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ bó ṣe yẹ"
"Mo bèèrè pé kí ni à ń ṣe níbí, mo ṣà ń gbọ́ tí àwọn dókítà náà ń kùn, wọ́n ṣà ń sọ pé ó wà ńbẹ̀, àwọn kan wá mí kanlẹ̀ lára wọn.
"Mi ò tọ̀, àìtọ̀ mi ló jẹ́ kí wọ́n gbé mi lọ sí yàrá àyẹ̀wò, wọ́n ní wọ́n fẹ́ pe èyí tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa tẹ́lẹ̀ níjà láti lè ri pé ó ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ padà."
Afolayan ní wọ́n ṣe oríṣiríṣi àyẹ̀wò fún òun tó fi di ọjọ́ kejì ṣùgbọ́n nígbà tó yá ni wọ́n sọ fún òun pé máa bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe dialysis.
"Mo bèèrè pé kí ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ nítorí ohun tí a jọ sọ kọ́ nìyẹn àmọ́ wọ́n ní ohun tí mà á ṣe nìyẹn nítorí mi ò tọ̀, pé ìtọ̀ kò jáde."
Ó ṣàlàyé pé àwọn dókítà náà sọ fún òun pé kíndìnrín tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa tẹ́lẹ̀ ń bá èyí tí wọ́n yọ kẹ́dùn ni kò ṣe ì tíì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ bó ṣe yẹ.
Ó ní òun bèèrè pé ṣé kò sí nǹkankan tó ṣe kíndìnrín náà, tí wọ́n sì sọ fún òun pé kò sí nǹkankan tó ṣe é, pé ó máa padà jí.
'Lẹ́yìn tí mo ti ṣe dialysis mẹ́rìndínlógún ni mo lọ ṣe àyẹ̀wò nílé ìwòsàn míì ni mo mọ̀ pé wọ́n ti yọ kíndìnrín mi méjéèjì'
Ó fi kun pé lẹ́yìn tí òun ṣe dialysis ní bíi ẹ̀ẹmẹ̀fà ni wọ́n sọ fún òun láti máa lọ sílé àmọ́ lẹ́yìn tí òun ṣe dialysis ní ìgbà mẹ́rìndínlógún ni èèyàn kan ta òun lólobó láti lọ sẹ àyẹ̀wò ní ibòmíràn.
Ó ní ibi tí òun ti ṣe àyẹ̀wò míì ni àwọn ti ṣàwárí rẹ̀ pé kò sí kínìnrín kankan nínú òun mọ́, pé wọ́n ti yọ kíndìnrín méjéèjì mọ́ òun lọ́wọ́.
"Mo lọ bèèrè fún dókítà tó ṣe iṣẹ́ abẹ mi gangan, mo bèèrè pé ṣé kò sí àṣìṣe kankan nígbà tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ abẹ náà lọ́wọ́, ó ní kò sí ohunkóhun tó ṣẹlẹ̀.
"Ó sọ fún mi pé ìmọ̀ràn tí òun máa gbà mí ni láti lọ ṣe pàṣípààrọ̀ kíndìnrín, pé ó sì máa ná mi tó mílíọ̀nù márùndínlọ́gbọ̀n sí ọgbọ̀n mílíọ̀nù náírà."
Afolayan sọ pé ohun tó kọ òun lóminú jùlọ ní pé níbo ni òun yóò wá ẹni tó máa fún òun ní kíndìnrín sí àmọ́ dókítà náà ní kí òun kàn wá owó wá, àwọn máa mọ bí kíndìnrín ṣe máa jáde.
"Ọ̀rọ̀ ṣe bákanbákan lára mi nítorí ṣé kíndìnrín jẹ́ nǹkan tí wọ́n kàn ń rà lọ́jà níbẹ̀ láti lọ ṣe àyẹ̀wò ní ilé ìwòsàn míì tí a sì ri pé kò sí kíndìnrín kejì gan níbẹ̀."
'Àwọn dókítà kò fẹ́ buwọ́lu lẹ́tà mi nítorí ìwé ẹ̀sùn tí ẹ̀gbọ́n mi kọ tako dókítà tó ṣiṣẹ́ abẹ mi'
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ohun tó bí wàhálà láàárín òun àti ilé ìwòsàn náà, ó ní ẹnìkan sọ pé òun fẹ́ ṣe ìrànlọ́wọ́ fún òun lọ́dọ̀ gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti láti rí owó tí òun fi máa ṣe iṣẹ́ abẹ gbà.
Èyí tó sì sílò kí àwọn gba lẹ́tà láti ilé ìwòsàn náà ṣùgbọ́n nítorí pé ẹ̀gbọ́n òun ti kọ ìwé ẹ̀sùn sí ọ̀gá ilé ìwòsàn náà, wọn kò fẹ́ fún òun ní lẹ́tà náà.
"Wọ́n sọ pé àwọn kò ní buwọ́lu lẹ́tà nítorí ìwé ẹ̀sùn tí a ti kọ èyí ló sì mú kí ìyàwó mi fárígá pé gbogbo èèyàn ló máa báwa dá sí ọ̀rọ̀ náà.
"Ọ̀gá ilé ìwòsàn EKSUTH, CMD ló pe dókítà tó ṣiṣẹ́ abẹ mi fúnra rẹ̀ pé kó buwọ́lu lẹ́tà àmọ́ ó ní òun ti lọ sílé.
Afolayan ṣàlàyé pé nígbà tí àwọn fi máa padà dé ilé ìwòsàn lọ́jọ́ kejì, wọ́n ti pààrọ̀ ohun tí wọ́n kọ sínú lẹ́tà tẹ́lẹ̀.
"Wọ́n kọ sínú lẹ́tà tuntun pé ìjàmbá ọkọ̀ ló gbé wá sí ilé ìwòsàn, pé mo ṣe iṣẹ́ abẹ, iṣẹ́ abẹ náà sì lọ bó ṣe yẹ, wọ́n sì dá mi sílẹ̀ láti máa lọ sílé.
"Pé nígbà tí mo délé ni wọn ri pé mi ò lè tọ̀, èmi tó jẹ́ pé láti ibi tí a ti ṣe iṣẹ́ abẹ ni mi ò ti rí ìtọ̀ tọ̀ àti pé kíndìnrín mi lẹ̀pọ̀."
Afolayan ní dialysis tí òun ń ṣe ló jẹ́ kí òun ṣì wà láyé, tí ẹ̀rù sì ń ba òun lójoojúmọ́ pé kí òun má jẹ̀ ẹ́ aláìsí lọ́jọ́ àìpé.
Kí ni ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti sọ?
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti sọ pé àwọn ti gbọ́ sí ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n sì ti gba iṣẹ́ lọ́wọ́ dókítà tó ṣe iṣẹ́ abẹ náà.
Ìjọba ní àwọn máa san owó láti ṣe pàṣípààrọ̀ kíndìnrín Afolayan Àmọ́ Afolayan ń bẹ̀bẹ̀ pé òun kò fẹ́ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ náà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.