Ìyá mi máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ pé mi ò lè jọba nítorí n kò kọlà, torí náà, n kò rí ara mi bíi ẹni tó máa jọba - Soun Ogbomoso

Ìyá mi máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ pé mi ò lè jọba nítorí n kò kọlà, torí náà, n kò rí ara mi bíi ẹni tó máa jọba - Soun Ogbomoso

Soun ìlú Ogbomoso, Ọba Ghandi Olaoye ti sọ pé òun kò mọ̀ pé òun le jẹ Ọba ìlú Ogbomoso nítorí òun kò kọ ilà ìdílé àwọn.

Ọba Ghandi ní lóòótọ́ ni òun mọ̀ pé ọmọọba lòun nítorí ohun tí òun gbọ́njú bá nìyẹn ṣùgbọ́n ìyá òun máa ń sọ pé òun kò lè jọba nítorí òun kò kọ ilà nígbà tí òun wà lọ́mọdé.

Ó ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò tilẹ̀ mọ̀ pé ọmọọba lòun kí òun tó dé orí ìtẹ́ àwọn babańlá rẹ̀ nítorí òun kìí sábà sọ fáwọn èèyàn àyàfi tí ọ̀rọ̀ bá kan ọ̀rọ̀.

"Mi ò kìí sọ fún àwọn èèyàn pé ọmọba ni mí àyàfi tí ọ̀rọ̀ bá débẹ̀."

"Mi ò kí ṣe ọba tó kàn fẹ́ máa ta ilẹ̀, gba ìyàwó oníyàwó"

Ọba Ghandi Olaoye sọ pé ọ̀pọ̀ ìpèníjà ni òun ti kojú lẹ́nu ìgbà tí òun ti dórí ipò ṣùgbọ́n òun kò rí ọ̀pọ̀ wọn bíi ìṣòro.

Ó fi kun pé òun gbàgbọ́ pé àwọn máa la àwọn ìpèníjà bẹ́ẹ̀ kọjá nítorí àwọn àtúnṣe tí òun ń ṣe kìí ṣe ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe tẹ́lẹ̀.

Lórí àfojúsùn fún ìlú Ogbomoso, ó ní ọ̀pọ̀ ohun ìdàgbàsókè ni òun ní fún Ogbomoso nítorí òun rí ipò ọba gẹ́gẹ́ bí ipò aṣíwájú èyí tó sì ń ṣe atọ́nà ọ̀pọ̀ ìgbésẹ̀ tí òun ń gbé láti ìgbà tó ti wà lórí ipò náà.

Ó ní ọ̀pọ̀ àtúntò ni òun ti gbéṣe láti ìgbà tí òun ti gbapò Soun Ogbomoso.

"Emi ko ri ara mi bii ọba ti yoo maa gba iyawo, ta ilẹ ilu, rara o.

Mo ri ipo ọba bii ipo asiwaju to n dari nnkan"

"Ọjọ ti wọn fi mi jẹ ọba ni ọjọ manigbagbe julọ ninu aye mi"

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ mánigbàgbé láti ìgbà tó ti jẹ oyè, Soun ìlú Ogbomoso, Ọba Ghandi Olaoye sọ pé ọjọ́ tí wọ́n fi òun jẹ oyè gan-an ló jẹ́ ọjọ́ náà fún òun.

Ó ní ọjọ́ kejì tí òun balẹ̀ láti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà sí ìlú Ogbomoso nítorí ọkọ̀ òfurufú helicopter ni òun gbé, tó sì jẹ́ pé ibẹ̀ ni òun gba lọ sí ààfin láti lọ gba adé.

"Wọ́n ti sọ fún mi pé ọ̀kan nínú àwọn tá jọ du oyè ti gba ilé ẹjọ́ lọ, wí pé wọn ò ní gbà ka ṣe kíni náà.

"Bí mo ṣe balẹ̀ sí Grammar School ni wọ́n tètè gbé mi lọ sí ààfin, ká ní pé a ò jẹ oyè náà lọ́jọ́ yẹn, bóyá a ṣì máa wà lẹ́nu ẹ̀ dìsín."

O fikun pe to ba jẹ pe oun ko tẹsiwaju lati jẹ ọba naa lasiko ọhun ni, o see se kawọn si wa lori ọrọ naa nile ẹjọ di akoko yii.

"Awọn eeyan wa mọ awọn agbebọn, aarin wa ni wọn maa n ko awọn eeyan ti wọn ba ji gbe wa, ẹni ti a ko mọ isẹ to n se, ti a ba sọ fun awọn ọlọpaa, laarin osu meji si mẹta, ọrọ igbesunmọmi yoo kasẹ nilẹ."

Ọba Ghandi Laoye, nigba to n sọrọ nipa iwa igbesunmọmi, salaye pe aarin ara wa ni awọn agbebọn naa wa.

Awọn eeyan wa kan lo n se igbesunmọmi, o si yẹ ka maa tu asiri wọn.

"Awọn eeyan wa mọ wọn, wọn mọ awọn ti wọn n se e.

O si yẹ ka maa fi ọrọ wọn to awọn agbofinro leti tori aarin wa naa ni wọn maa n ko awọn eeyan ti wọn ba ji gbe wa.

Ti a ba bẹrẹ si sọ fun awọn ọlọpaa nipa wọn, ẹni ti a ko mọ isẹ to n se, ti a ba sọ fun awọn ọlọpaa

Ẹ ri pe laarin osu meji si mẹta, ọrọ igbesunmọmi yii yoo kasẹ nilẹ."