You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èwo nínú àwọn ẹ̀dùn ọkàn àwọn olúwọ́de #EndSARS lọ́dún 2020 n'ìjọba ti ṣe àmúṣẹ rẹ̀ lẹ́yìn ọdún márùn ún?
Ní oṣù Kẹwàá, ọdún 2020 ni ìwọ́de #EndSARS bẹ̀rẹ̀ káàkiri ìpínlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn náà èyí tí àwọn ọ̀dọ́ ṣe agbátẹrù rẹ̀ nígbà náà ni láti bèèrè fún fífi òpin sí bí àwọn ọlọ́pàá lẹ́ka tó máa ń rí sí ìwà olè jíjà, ìyẹn Special Anti-Robbery Squad, SARS, ṣe máa ń tẹ ẹ̀tọ́ àwọn ọ̀dọ́ lójú mọ́lẹ̀.
Ṣáájú ìwọ́de náà ni onírúurú ẹ̀sùn ti ń wáyé nípa àwọn ọlọ́pàá SARS pé wọ́n ń ṣekúpa àwọn ọ̀dọ́ lọ́nà àìtọ́, tí wọ́n sì máa ń dá àwọn ọ̀dọ́ lọ́nà, gba gbogbo ìní tí wọ́n bá kó dání.
Ní ọjọ́ Kẹta, oṣù Kẹwàá, ọdún 2020 ni fídíò kan gba orí ayélujára èyí tó ṣàfihàn báwọn ọlọ́pàá SARS ṣe ṣekúpa ọkùnrin kan ní ìpínlẹ̀ Delta tí wọ́n sì wa ọks rẹ̀ lọ.
Ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹwàá ni fídíò míì tún gba orí ayélujára nígbà tí ẹ̀mí ọ̀dọ́kùnrin míì tó jẹ́ olórin tún ti ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá SARS bọ́ ní ìpínlẹ̀ Eko.
Èyí ló mú àwọn ọ̀dọ́ dìde láti ṣe ìfẹ̀hónúhàn pé kí ìjọba àpapọ̀ wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí àwọn ọlọ́pàá náà, tí wọ́n sì pè fún pé kí ìjọba àpapọ̀ tú ikọ̀ náà ká.
Ọjọ́ Kẹjọ oṣù Kẹwàá ni ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn láti fòpin sín ìwà ìpànìyàn àwọn SARS yìí bẹ̀rẹ̀ tó sì wá sópin ní ogúnjọ́, oṣù Kẹwàá nígbà tí àwọn ọmọ ogun fi ìbọn tú àwọn olùwọ́de tó wà ní agbègbè Tollgate Lekki ní ìpínlẹ̀ Eko ká.
Kí ni àwọn nǹkan tí àwọn olùwọ́de náà ń bèèrè fún?
Nǹkan márùn-ún gbòógì ni àwọn olùwọ́de tí wọ́n ṣe ìfẹ̀hónúhàn #EndSARS bèèrè fún lọ́wọ́ ìjọba lásìkò náà.
Lára ohun tí wọ́n bèèrè fún ni pé kí ìjọba tú ikọ̀ SARS ká nítorí àwọn ọṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe àti pé wọ́n ti yẹ̀bá lórí ìdí tí ìjọba fi gbé wọn kalẹ̀.
Wọ́n tún ní kí ìjọba tú gbogbo àwọn èèyàn tí ikọ̀ SARS ti fi dí àhámọ́ sílẹ̀ àti pé ìjọba gbọdọ̀ pèsè ẹ̀bùn gbà má bínú fún gbogbo ẹbí àwọn èèyàn tí ẹ̀mí wọn ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá lọ́nà àìtọ́.
Wọ́n ní kí ìjọba gbé ìgbìmọ̀ kan dìde láàárín ọjọ́ mẹ́wàá láti ṣe ìwádìí gbogbo àwọn ìwà kò tọ́ tí wọ́n fi kan àwọn ọlọ́pàá náà àti láti fi ìyà tó bá tọ́ jẹ èyí tí adé ìwà ìbàjẹ́ bá ṣí mọ́ lórí.
Bákan náà ni wọ́n bèèrè pé kí ìjọba ri pé wọ́n ṣe àyẹ̀wò tó péye fún àwọn ọlọ́pàá tó wà lábẹ́ ikọ̀ SARS kí wọ́n tó kó wọ́n tó kó wọn darapọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀ka míì.
Ìbéèrè tó gbẹ̀yìn ni pé kí ìjọba fi kún owó oṣù àwọn ọlọ́pàá lójúnà àti lè ri pé owó oṣù wọn ń tó wọn ná.
Èwo ni ìjọba ṣe àmúṣẹ nínú àwọn ìbéèrè yìí?
Nígbà tó di ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹwàá, ìjọba kéde tútú ikọ̀ SARS ká èyí tí àwọn olùwọ́de náà rí gẹ́gẹ́ bí ohun ìwúrí àti pé ìwọ́de àwọn ń so èso rere.
Ṣùgbọ́n ìkéde yìí kò ṣe ìdádúró àwọn olùwọ́de náà nítorí ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ṣì tẹ̀síwájú.
Ní ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹwàá ni ìgbìmọ̀ kan tí ìjọba àpapọ̀ gbé dìde láti rí sí àwọn ìbéèrè àwọn olùwọ́de ọ̀hún èyí tí Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá nígbà náà, Mohammed Adamu darí rẹ̀ kéde àwọn ìgbésẹ̀ kan láti kojú ẹ̀sùn àwọn olùwọ́de ọ̀hún.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ààrẹ àná, Femi Adeshina fi léde sọ pé ìgbìmọ̀ tí ìjọba àpapọ̀ gbé kalẹ̀ náà panupọ̀ láti tú SARS ká.
Ó ní ìgbìmọ̀ náà gbà pé ẹ̀tọ́ gbogbo ọmọ Nàìjíríà ni láti ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn, àti pé gbogbo ẹ̀mí ọmọ Nàìjíríà ló ṣe kókó, tó sì yẹ láti máa dá ààbò bò ní gbogbo ìgbà.
Àtẹ̀jáde náà sọ pé gbogbo ìbéèrè máráàrùn táwọn olùwọ́de ẹ̀hún ń bèèrè fún ni ìjọba máa ṣe àti pé wọ́n máa gbé àwọn olùwádìí dìde láti ìwádìí ìwà títẹ ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn lójú mọ́lẹ̀ tí wọ́n fi kan àwọn ọlọ́pàá náà.
Lẹ́yìn náà ni àwọn ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan gbé àwọn ìgbìmọ̀ olùwádìí dìde láti ṣe ìwádìí ìwà títẹ ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn lójú mọ́lẹ̀ tí wọ́n fi kan àwọn ọlọ́pàá náà.
Ní ìpínlẹ̀ Oyo, Gómìnà Seyi Makinde kéde fífún ọmọkùnrin kan, Samuel Ogundeji gba ẹ̀bùn ọkọ̀ ọ̀fẹ́ lẹ́yìn tí ìwádìí ìgbìmọ̀ tí ìjọba gbé kalẹ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ọlọ́pàá SARS ló ṣokùnfà bí ojú rẹ̀ ṣe fọ́.
Gómìnà Seyi Makinde kéde ẹ̀bùn náà lásìkò tó tẹwọ́ gba ìjábọ̀ ìgbìmọ̀ olùwádìí ọ̀hún lọ́dún 2022 ní Agodi, Ibadan.
Makinde tún jẹ́jẹ̀ẹ́ pé gbogbo àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ EndSARS lọ lọ máa rí ìdájọ́ òdodo gbà látọwọ́ ìjọba òun.
Ní ìpínlẹ̀ Eko, lọ́dún 2021 Gómìnà Babajide Sanwo-Olu fún ẹbí àwọn tí ọlọ́pàá SARS ṣekúpa èèyàn wọn ní ẹ̀bùn mílíọ̀nù mẹ́wàá mẹ́wàá.
Ìgbésẹ̀ náà ló ń wáyé lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ tí ìjọba gbé kalẹ̀ ri pé àwọn ọlọ́pàá náà jẹ̀bi, tí wọ́n sì lọ́wọ́ nínú ikú àwọn èèyàn náà.
Ìgbìmọ̀ náà tún ní gbo gbo àwọn ọlọ́pàá tó lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn ló gbọdọ̀ fojú winá òfin.
Ọdún 2021 kan náà ni Gómìnà Nyesom Wike ti ìpínlẹ̀ Rivers gba ìjábọ̀ ìgbìmọ̀ tí wọ́n gbé kalẹ̀, tó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣe àmúṣẹ gbogbo ìjábọ̀ ìgbìmọ̀ ọ̀hún.
Wo àwọn orílẹ̀ èdè táwọn ọ̀dọ́ ti ń ṣíwájú ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn
- Madagascar
Ní oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2025 ni Ààrẹ Abdry Rajoelina ti orílẹ̀ èdè Madagascar tún ìgbìmọ̀ aláṣẹ rẹ̀ ká lẹ́yìn tí àwọn ọ̀dọ́ bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn tó lágbára gidi.
Ìwọ́de náà ló ń wáyé látàrí àìsi omo àti iná mọ̀nàmọ́ná.
Kò dín ní èèyàn méjìlélógún tó pàdánù ẹ̀mí won níbi ìwọ́de ọ̀hún, tí àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún sì farapa.
- Morocco
Lásìkò kan náà tí ìwọ́de wáyé ní Madagascar náà ni ó wáyé ní orílẹ̀ èdè Morocco.
Àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n pe ara wọn ní GenZ 212 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de náà látorí ìkànnì ayélujára TikTok àti Instagram láti bèèrè fún ètò ẹ̀kọ́ àti ìlera tó péye.
Olùwọ́de tó lé ní irinwó ni wọ́n ti nawọ́ gán lórí ìwọ́de náà nígbà olóòtú ìjọba, Aziz Akhannouch sì kéde pé òun ti ṣetán láti jíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn láti wá ojútùú sáwọn ìbéèrè wọn.
- Nepal
Ní oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2025 ni ìwọ́de ńlá wáyé ní orílẹ̀ èdè Nepal lẹ́yìn tí ìjoba orílẹ̀ èdè náà fi òfin de àwọn ìkànnì ayélujára.
Ìwọ́de náà ṣokùnfà ikú èèyàn méjìléláàádọ́rin, tí ọ̀pọ̀ sì farapa nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ sì lo dáná sun ilé aṣòfin orílẹ̀ èdè náà.
Èyí mú kí olóòtú ìjọba orílẹ̀ èdè Nepal, Sharma Oli kọ̀wé fi ipò rẹ̀ sílẹ̀.
- Indonesia
Lẹ́yìn tí àwọn aṣòfin ní orílẹ̀ èdè Indonesia kéde àti máa gba owó ilé ìgbé tí iye rẹ̀ tó $3,000 lóṣù yàtọ̀ sí owó oṣù wọn ni àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀ èdè náà bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de láti fẹ̀hònúhàn.
Èyí mú kí àwọn ọ̀dọ́ bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn tako ìjoba pé ìgbésẹ̀ náà ń kó ìnira bá aráàlú pàápàá lẹ́ka ètò ọrọ̀ ajé.
Ìwọ́de náà di ńlá lẹ́yìn tí àwọn ọlọ́pàá ṣekúpa ọlọ́kọ̀ kan ní olú ìlú orílẹ̀ èdè Indonesia, Jakarta.
Ààrẹ Prabowo Subianto rọ àwọn èèyàn láti ṣe sùúrù, kí wọ́n sì ní ìgboyà nínú ìṣèjọba òun.
- Kenya
Ní ọdún 2024 ni àwọn ọ̀dọ́ ṣe ìwọ́de ńlá ní orílẹ̀ èdè Kenya lẹ́yìn tí ìjọba gbé òfin kan dìde lórí owó orí.
Ní orí ayélujára ni àwọn ọ̀dọ́ ti wọ́n ń kó ara wọn jọ lórí ayélujára láti ọjọ́ Kẹsàn-án, osù Karùn-ún, ọdún 2024 tí wọ́n ti kéde owó orí náà kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de ní Nairobi, olú ìlú Kenya.
Ìwọ́de náà ṣokùnfà ikú ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá ṣíná ìbọn bolẹ̀ fún wọn lásìkò ìwọ́de náà.
Ìwádìí BBC lẹ́yìn ọdún kan tí ìwọ́de náà wáyé fi hàn pé àwọn ọlọ́pàá mọ̀ọ́mọ̀ ṣíná ìbọn bolẹ̀ fún àwọn olùwọ́de tí kò ni nǹkan ìjà ogun lọ́wọ́ ni.