You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
PDP tó jáwé olúborí l'Osun látòkè délẹ̀ fihàn pé àwọn ará Osún nígbàgbọ́ nínú mi gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà wọn - Adeleke
Gomina Ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke ti ṣe àjọyọ lori bi ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ Peoples Democratic Party, PDP ṣe ko ibo to pọ gidi gan ni Ìpínlẹ̀ naa.
Ati ninu idibo ile aṣofin ati idibo ti ipo Ààrẹ ni ẹgbẹ òṣèlú PDP ti jawe olubori ni Osun ti Gomina Adeleke si n rọ àwọn ara Ìpínlẹ̀ rẹ pe ki wọn tun jẹ ko ri bẹẹ lasiko idibo ti ile aṣofin Ìpínlẹ̀ náà.
Adeleke sọ eyi nigba to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sọ̀rọ̀ èyí ti oludije ti wọn dibo yan dari wọn wa ni ilu Ede to si n fi asiko naa dúpẹ́ lọwọ awọn ara Ìpínlẹ̀ Oṣun to si tun ṣèlérí lati tun Ìpínlẹ̀ naa ṣe.
"Lórúkọ gbogbo awọn oludije to jawe olubori, mo dupẹ lọwọ yin. Ẹ ti fi han fun gbogbo araye pe bibori taa bori lọdun to kọja jẹ òótọ́ ati afihan pe ifẹ araalu ni. Mo dupẹ pupọ lọwọ awọn eeyan daadaa ti Ìpínlẹ̀ Osun."
Adeleke ṣèlérí fun wọn pe PDP ko ni ja wọn kulẹ. O tun ke si awọn adari ẹgbẹ́ pe ki wọn tẹra mọ iṣẹ lati rii pe awọn ara Oṣun dibo fun PDP ninu idibo to n bọ.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lo jawe olubori ni gbogbo ipo aṣofin ati ni ẹkùn ìdìbò mẹsan to wa nibẹ.