Àṣẹ Trump lórí dídi ọmọ onílùú nípa ìbí, ẹ̀yà akọ àtabo àtàwọn ìwé àṣẹ wàá míì ti Ààrẹ Amẹ́ríkà tuntun pa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọjọ Aje ogunjọ oṣu kinni ọdun 2025 ni Donald Trump pada si ipo gẹgẹbi aarẹ kẹtadinlaadọta fun orilẹede Amẹrika.
Lati igba ti o si ti de ori ipo lo ti n ṣe awọn ikede loriṣiriṣi ati igbesẹ loniranran.
Eyi ni awọn pataki ninu awọn aṣẹ waa to ti buwọlu ati awọn igbesẹ miran to ti gbe:
Aṣẹ waa lati fopin si ọrọ ẹtọ ọmọonilu fun awọn ọmọ awọn ti ko lẹtọ igbelu
Trump ti gbe igbesẹ lati ṣe atunṣe ilana didi ọmọ onilu lorilẹede Amẹrika. O ti paṣẹ fun awọn ajọ lati dẹkun fifun awọn ọmọ ti awọn obi wọn ko lẹto igbelu tabi awọn to gba fisa fidihẹ lẹtọ lati di ọmọ onilẹ.
Itumọ eyi ni pe gbogbo awọn to maa n lọ bimọ lorilẹede Amẹrika ti ọmọ bẹbẹ yoo si di ọmọ onilu ko ni le ri anfani bẹẹ mọ.
Ọgbọn ọjọ ni wọn fun awọn ajọ ijọba gbogbo lorilẹede naa lati fi idi aṣẹ yii mulẹ.
Amọṣa o awọn onwoye ti sọ pe o ṣeeṣe ki ọrọ nipa aṣẹ yii o de ile ẹjọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aṣẹ waa lori ẹya akọ ati abo
Trump buwọlu iwe aṣẹ to ni pe ẹya akọ ati abo nikan ni ẹya iṣẹda ti ijọba orilẹede Amẹrika yoo da mọ o ni awọn ẹya yii ko ṣe e yipada nitoripe ninu iṣẹda ni wọn ti jẹyọ
Aṣẹ yii yoo ni ipa lori awọn ẹlẹya iṣakọ-n-ṣabo ati iṣabo-n-ṣakọ. Bakan naa ni yoo si tun ni ipa lori iwe irinna orilẹede naa.
Aṣẹ waa lati dẹkun bi awọn eeyan ṣe n wọ orilẹede Amẹrika
Aṣẹ waa yii kede aṣẹ ilu o fara rọ lori ilana iwọle-wọde lorilẹede Amẹrika. Bakan naa ni igbesẹ yii tunbọ ṣe atunto ẹnubọde orilẹede naa pẹlu awọn alamuleti rẹ, paapaajulọ orilẹede Mexico.
Aṣẹ waa lati da Tiktok pada si Amẹrika
Aarẹ Trump buwọlu iwe aṣẹ waa kan to fun ileeṣẹ ibanidọrẹ Tiktok ni afikun aadọrin ọjọ gẹgẹbi gbedeke lati tẹle ofin ti orilẹede naa gbe kalẹ pe ki wọn ta ileeṣẹ naa tabi ki wọn gbẹsẹ le.
Titi ẹnubode
Trump tun paṣẹ ki awọn ologun o ti ẹnubode orilẹede naa pa. O tka si awọn iwa ọdaran bii ogun oloro, fifi eniyan ṣe owo kotọ atawọwọn iwa ọdaran miran gẹgẹ bi oun to n gogo sii lorilẹede naa nitori bi awọn eeyan ṣe n wọle-wọde lai si ofin to ka wọn lọwọ ko.
Aṣẹ lati kuro ni ajọ ilera agbaye, WHO
Aṣẹ waa yii bẹrẹ igbesẹ ati yọ orilẹede Amẹrika kuro lagbo ajọ ilera agbaye.
Igba keji niyi ti Trump yoo maa ni ki Amẹrika kuro lajọ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn aṣẹ waa miran ti Aarẹ Trump tun buwọlu niwọnyii:
- Aṣẹ to kede awọn ẹgbẹ jagidijagan ati ẹgbẹ okunkun gbogbo gẹgẹ bi ẹgbẹ agbesunmọmi.
- Aṣẹ fun titẹsiwaju pẹlu kikọ awọn odi si ori aala orilẹede naa.
- Aṣẹ "remain in Mexico" tó da awọn aṣatipo lati orilẹede Mexico pada si orilẹede wọn.
- Aṣẹ waa to gbe ijiya idajọ iku kalẹ fun ọmọ ilẹ okeere ti ko ni iwe igbelu to ba daran ati ẹnikẹni to ba jẹbi ẹsun pipa agbofinro lorilẹede naa.
- Aṣẹ to fi idaduro si eto iranwọ fun awọn ilẹ okeere duro fun Trump lati ṣe agbeyẹwo awọn eto iranwọ gbogbo ti orilẹ Amẹrika n ṣe fawọn ilẹ okeere.
- Iwe aṣẹ lati yi orukọ agbami "Gulf of Mexico" pada si "Gulf of America"
Itusilẹ awọn to da wahala silẹ ni ile aṣofin 'Capitol building'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lara awọn igbesẹ ti Aarẹ Trump gbe bayii ni idariji fun nnkan bii ẹgbẹrun kan o le ẹgbẹta awọn ọmọlẹyin rẹ ti wọn fi panpẹ ofin gbe lasiko ti wọn ṣe iwọde onijagidijagan wọ ile aṣofin apapọ orilẹede naa lọdun 2021.
Latigbadegba ni Aarẹ Trump ti n kede faye pe igbekun lawọn ti wn mu lori iṣẹlẹ naa wa. Awọn bii ẹgbẹta ni wọn mu lọjọ naa fun kikọlu awọn agbofinro.












