Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
O di gbeere, o darinako, o tun doju ala firi
Olori Alufaa ijọ Aguda, Pope Francis ti jade laye o
Aarọ oni ọjọ Aje ni awọn alaṣẹ Vatican kede ipapoda oloogbe ọhun
Ẹni odun mejidinlaadọrun ni Pope Francis ki ọlọjọ to de
Ẹkunrẹrẹ itan igbeaye Alufaa na wa loju opo BBC Yoruba
_____________________________
Awọn ajinigbe tun ti ṣọsẹ nijọba ibilẹ Ekiti, to wa Nipinlẹ Kwara nibi ti wọn ti ji ọpọ eeyan gbe lọ
A gbọ pe ọkọ Sienna kan to n rinrinajo lati Abuja siluu Offa lawọn kọlọrọsi naa kọlu, ti wọn si ji gbogbo ero inu rẹlọ
Ẹni ti ọrọ naa ṣoju rẹ sọ fun BBC pe awọn ajinigbe ọhun ko awọn agbalagba to wa ninu ọkọ naa lọ amọ wọn fi awọn ọmọde silẹ
_____________________________
Ni Kenya
Ọmọ ọdun mẹrinla kan ti padanu ẹmi rẹ ẹyin ti kiniun kan lọ ka mọ inu ile ti wọn n gbe
Ajọ to n ri si orọ ẹranko niluu Nairobi sọ pe ile awọn ọmọ naa ko jinna si ibi ti awọn kiniun naa wa
Fun ẹkunrẹrẹ