Ta ni yóò wọlé àtúndì ìbò ààrẹ Liberia láàrin George Weah ati Joseph Boakai?

Ipalẹmọ ti bẹrẹ lori atundi ibo ipo aarẹ lorilẹ-ede Liberia, nibi ti Aarẹ George Weah to wa lori ipo naa lọwọlọwọ ati igbakeji aarẹ orilẹede naa tẹlẹ ri, Joseph Boakai, ti n dupo ọhun mọra wọn lọwọ.

Akọroyin BBC, Moses Garzeawu, to wa ni Olu ilu Liberia ni Moronvia, jábọ̀ pe awọn eeyan orilẹ-ede naa n ti reti ibo yii gidi, wọn si ti ṣetan lati di i lai yọ ẹnikẹni silẹ.

Ẹ o ranti pe eyi ni ibo aarẹ kẹrin ti yoo waye ni Liberia lẹyin ogun abẹle to fogun ọdun ja wọn, nibi ti eeyan igba ati aadọta (250) ti dagbere faye .

Oṣu kẹwaa ọdun 2023 yii ni ibo si ipo aarẹ naa ti kọkọ waye lorilẹ-ede Liberia, George Weah to n tukọ ilu naa lọwọ ni ibo ida mẹtalelogoji ati mẹjọ, (43.8) ṣugbọn ko de ida aadọta to yẹ ko ni lati maa ba ipo aarẹ naa lọ, eyi to fa a ti atundi ibo fi di dandan.

Joseph Boakai ni tiẹ ni ida mẹtalelogoji ati mẹta (43.4)

Yatọ si eyi, magomago tun pọ ninu ibo ti wọn di kọja naa gẹgẹ bi ajọ eleto idibo ibẹ ṣe sọ.

Wọn sọ ọ di mimọ pe mẹsan-an ninu awọn oṣiṣẹ ti wọn gba lati mojuto idibo naa ni ọwọ ofin ba nigba ti wọn tọwọ bọ apoti idibo.

Bakan naa ni Ajọ Iṣọkan Agbaye (UN), fidi ẹ mulẹ pe awọn ikọlu oriṣiiriṣii lo waye laarin awọn alatako lasiko ibo naa.

Awọn oludije mejeeji ni wọn wa ọna lati fa oju araalu mọra.

Boakai to ṣe igbakeji Aarẹ obinrin akọkọ nilẹ Adulawọ, Ellen Johnson Sirleaf n polongo pe oun yoo mu iṣẹ agbẹ ni koko toun ba di aarẹ,nnkan amayedẹrun yoo si pọ. Nigba ti Weah to ti figba kan jẹ gbajugbaja agbabọọlu loun yoo mu eto ẹkọ ni koko, iṣẹ yoo si pọ fawọn ọdọ lati ṣe.

Aago mẹjọ aarọ ni idibo yoo bẹrẹ lọjọ ibo, yoo pari laago mẹfa irọlẹ, oṣu kin-in-ni ọdun to n bọ ni wọn yoo si bura fẹni to ba jawe olubori .