You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kareem Benzema, atamátàsé Real Madrid gba àmì ẹ̀yẹ Ballon d'Or 2022
- Author, Olubayode Alebiosu
- Role, Broadcast Journalist
- Reporting from, Lagos
Gbajumọ agbabọọlu ọmọ orilẹede France, Kareem Benzema to n gba bọọlu jẹun ni ikọ Real Madrid lorilẹede Spain ni o gba ami ẹyẹ Ballon d’Or ti ọdun yii.
Igba akọkọ rẹ ree lati gba ami ẹyẹ yii.
Goolu mẹrinlelogoji ni Benzema gba sinu awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrindinlaadọta to gba ni saa bọọlu ọdun 2021-22 to kọja nibi to ti lewaju ikọ Real Madrid lati gba ife ẹyẹ Champions league ilẹ Yuroopu ati ife ẹyẹ La liga ti liigi orilẹede Spain.
Lionel Messi ni agbabọọlu to gba ami ẹyẹ yii nigba to pọju. Igba meje ọtọọtọ lo ti gba a. Lẹyin rẹ ni Christiano Ronaldo to gba a fun igba marun un ọtọọtọ, Michel Platini, Johan Cruyff ati Marco van Basten ti gba a nigba mẹta ọtọọtọ.
Sadio Mane, ọmọ Senegal to n gba bọọlu jẹun ni ikọ Bayern Munich bayii lẹyin to fi ikọ Liverpool to to wa ni saa to kọja silẹ lo ṣe ipo keji ti Kevin de Bruyne, ọmọ Belgium to n gba bọọlu jẹun ni Manchester city nilẹ Gẹẹsi ṣe ipo kẹta.
Agbabọọlu obinrin to tasansan julọ lọdun 2021-2022
Putellas, agbabọọlu obinrin fun ikọ obinrin Barcelona lo ṣi di ife ẹyẹ Ballon d’Or ti Obinrin mu gẹgẹ bi agbabọọlu to ta sansan julọ lọdun 2022.
Beth Mead, ọmọ ilẹ Gẹẹsi to n gba bọọlu jẹun ni ikọ obinrin Arsenal lo ṣe ipo keji si.
Beth Mead wa lara ikọ England to gba ife ẹyẹ Euro 2022 fawọn obinrin ilẹ Yuroopu loṣu diẹ sẹyin.
Ipo kẹrindinlogun ni Asisat Oṣoala ọmọ Naijiria wa gẹgẹ bi agbabọọlu obinrin to pegede lagbaye.
Manchester city lẹgbẹ agbabọọlu to pegede julọ fun saa ọdun 2021-22
Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester city lo gba ife ẹyẹ ẹgbẹ agbabọọlu to ta sansan julọ lọdun 2022.
Agbabọọlu Manchester city mẹfa ọtọọtọ lo wọ aṣekagba ipele n pele nibi ami ẹyẹ naa.
Kevin de Bruyne, Joao Cancelo, Riyad Mahrez, Erling Haaland, Phil Foden fun ipele ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ, nigba ti aṣọle wọn Ederson ṣe ipo kẹta ni ipele aṣọle to pegede julọ.
Liverpool lo gba ami ẹyẹ naa lọdun to kọja.
Agbabọọlu ọmọ France akọkọ ti yoo gba Ballon d’Or lẹyin ọdun 1998
Ọkọ ere idaraya ere sisa racing car ni wọn fi gbe ife ẹyẹ Ballon d’Or wọ gbagede ibudo ami ẹyẹ naa lọjọ Aje. Gbajumọ awakọsaregbayi ni torukọ rẹ n jẹ Esteban Ocon lo si wa ọkọ na wọ ibudo Theatre du Chatelet ti ayẹyẹ naa ti waye.
Benzema ni yoo jẹ ọmọ orilẹede France ti yoo tun gba ami ẹyẹ yii lẹyin ti Zinedine Zidane gba a lọdun 1998.
“Ami ẹyẹ to wa niwaju mi yii fun mi layọ gidigidi. Nigba ti mo wa ni kekere, alaa rere ti mo n ni nigba ewe ni. Mi o tẹti ninu ileoa rẹ. Ko si ohun ti ko ṣe e ṣe.” Ni ọr Benzama lẹyin to gba mi ẹyẹ yii.
Esi ami ẹyẹ Ballon d’Or tọdun yii
1. Karim Benzema (Real Madrid, France).
2. Sadio Mane (Bayern Munich, Senegal).
3. Kevin de Bruyne (Manchester City, Belgium).
4. Robert Lewandowski (Barcelona, Poland).
5. Mohamed Salah (Liverpool, Egypt).
6. Kylian Mbappe (Paris St-Germain, France).
7. Thibaut Courtois (Real Madrid, Belgium).
8. Vinicius Junior (Real Madrid, Brazil).
9. Luka Modric (Real Madrid, Croatia).
10. Erling Haaland (Manchester City, Norway).
11. Son Heung-min (Tottenham Hotspur, South Korea)
12. Riyad Mahrez (Manchester City, Algeria).
13. Sebastien Haller (Borussia Dortmund, Ivory Coast).
14. Fabinho (Liverpool, Brazil) ati Rafael Leao (AC Milan, Portugal).
16. Virgil van Dijk (Liverpool, Netherlands).
17. Luis Diaz (Liverpool, Colombia) ati Dusan Vlahovic (Juventus, Serbia) ati Casemiro (Manchester United, Brazil).
20. Cristiano Ronaldo (Manchester United, Portugal).
21. Harry Kane (Tottenham Hotspur, England).
22. Trent Alexander-Arnold (Liverpool, England) ati Phil Foden (Manchester City, England) ati Bernardo Silva (Manchester City, Portugal).
25. Joao Cancelo (Manchester City, Portugal) ati Joshua Kimmich (Bayern Munich, Germany), Mike Maignan (AC Milan, France), Antonio Rudiger (Real Madrid, Germany), Darwin Nunez (Liverpool, Uruguay) ati Christopher Nkunku (RB Leipzig, France).
Itan nipa Ballon d’Or lati ọdun 1956
Ami ẹyẹ Ballon d’Or wa fun agbabọọlu to ba ta sansan julọ laarin ọdun kan. Iṣedede wọn ni saa liigi ọdun 2021 si 2022 ni wọn fi ṣe igbelewọn wọn.
Ede faranse ni wọn fi pe e, itumọ rẹ si ni bọọlu ti a fi wura ṣe.
Ami ẹyẹ ti ileeṣẹ iwe iroyin kan ti orukọ rẹ n jẹ France Football bẹrẹ si ni fun awọn agbabọọlu ni.
Lọdun 1956 ni akọkọ rẹ kọkọ waye. Laarin ọdun 2010 si 2015, pẹlu adehun pẹlu ajọ ere bọọlu lagbaye, wọn da ami ẹyẹ naa pọ mọ ami ẹyẹ ami ẹyẹ bọọlu agbaye ti FIFA ti wọn da silẹ lọdun 1991. Amọṣa ajọṣepọ naa pari lọdun 2016, wọn si da ami ẹyẹ naa pada si orukọ to n jẹ lati ibẹrẹ, iyẹn Ballon d’Or ti FIFA naa si pada si orukọ ti oun naa n jẹ tẹlẹ.
Ayẹyẹ ami ẹyẹ Ballon d’Or tọdun 2022 ni ẹlẹkẹrindinlaadọrin iru ẹ ti yoo waye.
Stanley Matthews, ọmọ orilẹede England to n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Blackpool nigba naa lo kọkọ gba a lọdun 1956; Alfredo Di Stéfano lo gba a lọdun 1957 ti Raymond Kopa tẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid kan naa si gba a lọdun 1958.
Awọn yooku to ti gba ami ẹyẹ naa niwọnyii:
Alfredo Di Stéfano Real Madrid 1959
Luis Suárez Barcelona 1960
Omar Sívori Juventus 1961
Josef Masopust Dukla Prague 1962
Lev Yashin Dynamo Moscow 1963
Denis Law Manchester United 1964
Eusébio Benfica 1965
Bobby Charlton Manchester United 1966
Flórián Albert Ferencvarós 1967
George Best Manchester United 1968
Gianni Rivera Milan 1969
Gerd Müller Bayern Munich 1970
Johan Cruyff Ajax 1971
Franz Beckenbauer Bayern Munich 1972
Johan Cruyff Barcelona 1973
Johan Cruyff Barcelona 1974
Oleg Blokhin Dynamo Kyiv 1975
Franz Beckenbauer Bayern Munich 1976
Allan Simonsen Borussia Mönchengladbach 1977
Kevin Keegan Hamburger SV 1978
Kevin Keegan Hamburger SV 1979
Karl-Heinz Rummenigge Bayern Munich 1980
Karl-Heinz Rummenigge Bayern Munich 1981
Paolo Rossi Paolo Rossi 1982
Michel Platini Juventus 1983
Michel Platini Juventus 1984
Michel Platini Juventus 1985
Igor Belanov Dynamo Kyiv 1986
Ruud Gullit Milan 1987
Marco van Basten Milan 1988
Marco van Basten Milan 1989
Lothar Matthäus Internazionale 1990
Jean-Pierre Papin Marseille 1991
Marco van Basten Milan 1992
Roberto Baggio Roberto Baggio 1993
Hristo Stoichkov Barcelona 1994
George Weah Milan 1995
Matthias Sammer Borussia Dortmund 1996
Ronaldo Internazionale 1997
Zinedine Zidane Juventus 1998
Rivaldo Barcelona 1999
Luís FigoReal Madrid 2000
Michael Owen Liverpool 2001
Ronaldo Real Madrid 2002
Pavel Nedvěd Juventus 2003
Andriy Shevchenko Milan 2004
Ronaldinho Barcelona 2005
Fabio Cannavaro Real Madrid 2006
Kaká Milan 2007
Cristiano Ronaldo Manchester United 2008
Lionel Messi Barcelona 2009
Lionel Messi Barcelona 2010
Lionel Messi Barcelona 2011
Lionel Messi Barcelona 2012
Cristiano Ronaldo Real Madrid 2013
Cristiano Ronaldo Real Madrid 2014
Lionel Messi Barcelona 2015
Cristiano Ronaldo Real Madrid 2016
Cristiano Ronaldo Real Madrid 2017
Luca Modric Real Madrid 2018
Lionel Messi Barcelona 2019
Ami ẹyẹ naa ko waye lọdun 2020 nitori ajakalẹ arun COVID-19
Lionel Messi Barcelona 2021
Kareem Benzema Real Madrid 2022