A ti ṣetán láti kó ọkọ̀ tó ń lo iná ẹlẹ́tírìkì 100 wọ Nàìjíríà - Tinubu

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Bola Tinubu ti kéde pé àwọn máa kó àwọn ọkọ̀ tó ń lo iná ẹlẹ́tírìkì ọgọ́rùn-ún wọ Nàìjíríà lójúnà àti ṣe àmójútó ètò àyíká.

Tinubu ní kíkó àwọn ọkọ̀ náà wọlé yóò mú àdínkù tó lóòrìn bá àwọn nǹkan tó ń ba ojú ọjọ́ jẹ́ àti pé yóò pọkún ètò ìrìnnà Nàìjíríà.

Níbi ètò àpérò lórí àyípadà ojú ọjọ́ COP28 tó wáyé ní Dubai, United Arab Emirates ni Tinubu ti sọ̀rọ̀ náà.

Ó ní ìgbésẹ̀ yìí ṣàfihàn pé ìjọba òun ní ìfarajìn láti mú àyípadà bá àyíká léyìí tó ṣokùnfà tí àwọn ṣe ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àjọ Africa Carbon Market Initiative.

Àtẹ̀jáde kan tí agbenusọ Tinubu, Ajuri Ngalele fi léde ní èròńgbà ìṣèjọba tó wà lóde ni láti rí dájú pé àyíká Nàìjíríà wà lọ́nà tí yóò jẹ́ kí àwọn olùdókoòwò gbé okoòwò wá sí Nàìjíríà.

Bákan náà ni Ààrẹ Tinubu tún yan alága àjọ Federal Inland Revenue Service (FIRS), Zach Adedeji àti adarí àjọ tó ń rí sí àyípadà ojú ọjọ́ ní Nàìjíríà ìyẹn National Council on Climate Change, Dahiru Salisu gẹ́gẹ́ bí alága àjọ Nigeria Carbon Market Activation Plan.

Ó ní ìgbésẹ̀ náà tún jẹ́ ojúnà láti gbé Nàìjíríà àti ilẹ̀ Adúláwọ̀ lápapọ̀ síwájú nípa wíwá ojútùú sí àyípadà ojú ọjọ́, Tinubu rọ àwọn orílẹ̀ èdè yòókù nílẹ̀ Adúláwọ̀ láti wo àwòkọ́ṣe Nàìjíríà.

Ó ní kí àwọn orílẹ̀ èdè yòókù náà wo ọ̀nà tí wọ́n le gbà láti wá ojútùú sí àyípadà ojú ọjọ́.

Ó fi kun pé àwọn ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ láti pèsè ètò tí yóò mú ìgbéga àti ìlọsíwájú bá àwùjọ.