Àti fi iná mọ̀nàmọ́ná ṣọdún yóò mẹ́hẹ diẹ̀ fáwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Oyo, Osun, Ogun àti Kwara, ìdí rèé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ apinaka IBEDC ti ṣalaye idi abajọ ti ina ọba fi n ṣe ṣege ṣege lọwọ yii ni ipinlẹ Oyo, Osun, Ogun ati ipinlẹ Kwara.

IBEDC ni eyi ko ṣẹyin adinku to ti ba iwọn ina ti ileeṣẹ to n pese ina mọnamọna n fun ileeṣẹ apinaka ọhun lẹnu lọọlọ yii.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ naa fi sita l'Ọjọru ni o ti ṣalaye pe adinku to ba ina tawọn n ri gba lati pin naa lo ṣakoba fun ipinlẹ Oyo, Ogun, Osun ati ipinlẹ Kwara.

IBEDC tọrọ aforijin lọwọ awọn onibaara wọn lori ina ọba to n ṣe ṣege ṣege kaakiri ipinlẹ mẹrin tọrọ kan.

Ileeṣẹ naa sọ ninu atẹjade to fi sita wi pe awọn ti n ba ileeṣẹ amunawa TCN ati NISO sọrọ lati wa ojutuu si nnkan to ṣokunfa adinku to ba ina ti wọn n fawọn ipinlẹ mẹrẹẹrin naa.

IBEDC ni ọwọ ina tawọn n ri gba lasiko yii lawọn n pin fawọn onibaara kaakiri ipinlẹ Oyo, Ogun, Osun ati Kwara.

Ileeṣẹ naa ni deedee lawọn n pin ọwọ ina tawọn n ri gba lai ṣegbe lẹyin adugbo tabi ipinlẹ kan.

IBEDC wa rọ awọn onibaara wọn lati ṣe suuru titi ti ileeṣẹ TCN yoo fi wa ojutuu si iṣoro ti wọn n koju lọwọ yii lori ọrọ ina ọba.

''A mọ riri awọn onibaara wọn pẹlu suuru ti wọn ti ni, a o maa fi to wọn leti bi gbogbo nnkan ṣe n lọ lori ọrọ ina yii,'' IBEDC lo sọ bẹẹ.

Ẹwẹ, ileeṣẹ IBEDC ti sọ pe oun ti n ṣe akitiyan lori ọna ati mawọn to n jale ina ọba, awọn to n ba opo ati waya ina jẹ to fi mawọn to n ṣekọlu sawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ IBEDC.

Ileeṣẹ naa sọ pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ yoo foju bale ẹjọ.

IBEDC fidi rẹ mulẹ pe awọn ti gbe Arabinrin Adebola Arowona to n gbe ni Oluyole Estate niluu Ibadan, lọ sile ẹjọ lori ẹsun wi pe o ṣẹkọlu sawọn oṣiṣẹ IBEDC, o si tun ba ọkọ wọn jẹ.

IBEDC ni awọn oṣiṣẹ awọn n ṣayẹwo kaakiri nigba ti wọn ri pe Arabinrin Arowona ti tọwọ bọ mita ina ile rẹ.

Ileeṣẹ naa ni Arabinrin yii ko jẹ kawọn oṣiṣẹ IBEDC ja ina ile rẹ, o si tun ti oṣiṣẹ wọn to wa lori aga lulẹ.

Wọn tun fẹsun kan obinrin naa pe o tun digbaju lu oṣiṣẹ IBEDC miran.