You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba Kwara já ìràwọ̀ olùkọ́ tó yasọ mọ́ àgùnbánirọ̀ lára
Ijọba ipinlẹ Kwara ti ṣeto ijiya to tọ fun olukọ kan, Hajia Hamzat Fatimoh Nike to ya aṣọ mọ agunbanirọ kan lọrun.
Agunbanirọ ọhun ti wọn fi orukọ rẹ pamọ lo n sinru ilu labẹ idari ajọ NYSC, ni ile ẹkọ girama Government Day Junior Secondary School to wa ni Kulende, niluu Ilorin.
Lara awọn tọrọ naa ṣoju wọn sọ fun BBC Yoruba pe, l’Ọjọbọ, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2024, ni ọrọ yi waye nile ẹkọ girama ọhun.
Latigba naa ni ijọba Kwara ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, koda ti wọn tun gbe igbimọ oluwadi dide lati mọ igbesẹ to tọ lati gbe.
Ninu atẹjade kan ti kọmisanna to n ri seto ẹkọ, Hajia Sa’adatu Modibbo Kawu ati alaga ajọ olukọni ni ipinlẹ Kwara, Mallam Bello Tauheed Abubakar tọwọ bọ l’Ọjọru, ọjọ kẹrin, oṣu Kejila, ijọba sọ pe igbimọ oluwadii t’ohun gbe kalẹ lori ọrọ naa ti rii pe olukọni naa jẹbi.
Àwọn ẹ̀sẹ̀ àti ìjìyà Olùkọ́ Hamzat Fatimah Nike
Igbimọ oluwadii naa sọ pe, Hajia Hamzat Fatimoh Nike jẹbi ẹsun ija jija lẹnu isẹ, sisọ ọrọ odi ati aibọwọ fun ami idanimọ orilẹ-ede Naijiria ti aṣọ arabinrin agunbanirọ naa duro fun.
Wọn ni ihuwasi rẹ tako ofin iṣẹ ijọba, fun idi eyi, wọn ja irawọ rẹ silẹ pẹlu ipele, iyẹn gireedi meji.
Ko tan sibẹ o, atẹjade naa sọ pe wọn yoo gbe olukọ naa kuro nibi to ti n ṣiṣẹ lọwọlọwọ, yoo si tun wa labẹ idanilẹkọọ ati igbaninimọran fun ayipada ọkan.
Siwaju sii, ijọba Kwara ni ohun ko nii fọwọ rirọ mu irufẹ iwa bẹẹ labẹ bo se wu kori.
Ijọba koro oju si iwa olukọ naa, o si fi da ajọ agunbanirọ, NYSC loju pe iwa bẹẹ kii ṣe iwa awọn eniyan ipinlẹ ohun, ati pe iru rẹ, ko ni ṣẹlẹ mọ.
Wọn rọ gbogbo olukọ ipinlẹ ọhun lati bọwọ fun ofin ni gbogbo igba, ki wọn si ṣe iṣẹ wọn ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin iṣẹ ijọba.
Wọn fi kun-un pe ijọba yoo tẹsiwaju lati fi kikọ awọn olukọni ni ẹkọ ati ilana ikọni ni baada.
NSYC gbé ìpinu rẹ̀ kalẹ̀
BBC Yoruba ba agbẹnusọ ajọ NYSC nipinlẹ Kwara, Morakinyo Oladipo sọrọ lori ago, o fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o sọ pe ajọ naa ko nii laju rẹ silẹ ki wọn maa tabuku awọn agunbanirọ nipinlẹ naa.
O ni ohun to sẹlẹ ni pe arabinrin agunbanirọ naa n lọ si ipade awọn agunbanirọ (CDS), pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ yooku, lati ile ẹkọ Governement Day Secondary School. Irinajo wọn si gbe wọn gba iwaju ẹka ti awọn akẹkọọ to wa ni ipele kekere, Junior Secondary School.
“Igba ti wọn n pada lọ ni awọn olukọ ile ẹkọ naa da wọn lọna pe wọn ko ki awọn nigba ti wọn n kọja lọ.
"Awọn agunbanirọ naa dahun pe awọn ki wọn sugbọn ọrọ naa di rogbodiyan ti Hajia Hamzat Fatimoh Nike si lu agunbanirọ naa, ko to tun fa aṣọ ya mọ-ọn lọrun.”
Agbẹnusọ naa jẹ ko di mimọ pe ọga agba pata fun ajọ NYSC ni Naijiria ṣabẹwo si ile-ẹkọ naa lati koro oju si iṣẹlẹ ọhun.
“Ni bayii gbogbo agunbanirọ to wa ni ile-ẹkọ naa ni a ti ko kuro lati dẹkun iru iwa bẹẹ ati lati ba ẹni to ṣẹlẹ si kẹdun,” Oladipo sọ fun BBC.
Agbẹnusọ naa kọ lati darukọ arabinrin agunbanirọ ọhun, pẹlu bo ṣe jẹ ko di mimọ pe “didarukọ rẹ lodi si ofin iṣẹ wa”.
Agùnbánirọ̀ náà kìí fi iṣẹ́ rẹ̀ ṣeré
Nigba ti BBC Yrouba ṣabẹwo si ile-ẹkọ girama naa, ọga agba ti agunbanirọ ọhun wa labẹ rẹ, Alhaji Ishola Abdulateef, sọ pe ọdọ oun ni wọn pin agunbanirọ ọhun si, ṣugbọn olukọ to fa aṣọ ya mọ-an lọrun ko si labẹ oun, nitori girama agba lo wa.
Abdulateef jẹ ko di mimọ pe ọmọluabi ni agunbanirọ ọhun, ati pe kii fi iṣẹ rẹ ṣere rara.