You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Mo kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní fásitì, àmọ́ aṣọ ìtìjú mi ti fàya bí mo ṣe n fi súùtù kiri mọ́ín-mọ́ín'
Akẹkọjade fasiti ilu Ilorin ni Gideon Kupolati, ko to o bẹrẹ si ni maa fi suutu, ti awọn alakọwe n wọ lọ si ibi’ṣẹ kiri mọinmọin kaakiri ilu Ilorin nipinlẹ Kwara.
Ninu ifrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba, Arakunrin Kupolati sọ pe lọdun 2021 nigba ti oun wa ni ipele kẹta ninu eto ẹkọ oun ni Fasiti, ni oun ronu nnkan ti oun le maa ṣe lati maa fi mu owo wọle.
Lara iwadii rẹ lo ti kiyesi pe ko si ẹni to n ta mọin-mọin ninu ọgba ile ẹkọ naa, eyi si lo mu ko pinnu lati maa ta a.
Awọn ọrẹ rẹ lo kọkọ n ra ọja lọwọ rẹ, ko to o di pe o di ilumọọka.
Ọgbẹni Kupolati ṣalaye pe iya oun kọkọ tako mọin-mọin tita, “wọn sọ fun mi pe iwe ni awọn ran mi lọ ọka ni fasiti, kii sẹ mọin-mọin”.
“Ṣugbọn mo pinnu lati tẹsiwaju nitori pe, kii ṣe gbogbo igba ni maa ma beere owo nile, ati pe lilọ ile ẹkọ ni Naijiria ko tumọ si pe, eeyan yoo bori ìṣẹ́.”
O ni ọmọ ọdun mọkanla ni oun ti bẹrẹ ounjẹ sie nile, ti iṣẹ mọin-mọin naa si n gbọ bukaata oun.
“Mi o fẹ iṣẹ alakọwe kankan, gbogbo anfaani ti mo n wa, idi mọin-mọin tita ni mo ti n wa a.”