You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kóòtù yọ̀ǹda ọkùnrin tó fi ìbálòpọ̀ pa ìyàwó rẹ̀, ariwo ta
Ikilọ: Awọn ọrọ ti o le ma nifẹẹ si wa ninu iroyin
Bi ọkunrin ba fipa ba iyawo rẹ lo pọ ni India, ọkunrin naa ko jẹbi. Ofin wọn ni.
Ofin yii ko ṣẹṣẹ ri bẹẹ ni India, o ti wa tipẹ. Ṣugbọn ohun to fa awuyewuye bayii ni ti ọkunrin ẹni ogoji ọdun to ba iyawo rẹ lo pọ ti obinrin naa si ku, ṣugbọn ti kootu da a silẹ pe ko maa lọ layọ ati alaafia.
Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an?
Lọjọ kọkanla, oṣu Kejila ọdun 2017 ni ọkọ iyawo naa ti wọn ni awakọ ero ni, nawọ ere ifẹ si iyawo rẹ.
Gẹgẹ bi awọn agbẹnusọ lori ọrọ yii ṣe wi, iyawo naa ko fẹẹ gba, ọkọ si fi tulaasi ṣe kinni pẹlu rẹ, eyi to fa aarẹ ati inira fun obinrin naa.
Wọn ni bi ọkọ ṣe jade lọjọ keji ni iyawo to n jẹ irora yii rọju lọ sọdọ aburo ọkọ rẹ obinrin lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ.
Aburo ọkọ naa ati ọkunrin kan ni wọn jọ gbe e lọ sileewosan, ṣugbọn ko pẹ to debẹ to fi dagbere faye.
Alaye ti wọn ni iyawo ṣe lasiko to n ku lọ ni pe ibalopọ ti ọkọ fipa ṣe foun lo fa wahala, bẹẹ naa lo si ṣe sọ ọ fun awọn ọlọpaa nigba to pada di ariwo.
Wọn ṣe ayẹwo oku naa, o si fi han pe ohun ti oyinbo n pe ni ''Peritonitis'', to tumọ si ki ijamba ṣẹlẹ si inu ati oju ara eeyan, lo pa iyawo yii.
Ọrọ naa ni wọn tori ẹ mu ọkọ, to si de kootu lati rojọ lori ifipabanilopọ ati ipaniyan.
Ọdun 2019 ni idajọ waye, adajọ igba naa si sọ pe ọkọ iyawo jẹbi ẹsun mejeeji.
O paṣẹ pe ki ọkunrin yii lọọ ṣẹwọn ọdun mẹwaa fun ẹsun ifipabanilopọ ati ipaniyan.
Adajọ sọ pe a ki i ba ni tan ka fani nitan ya, ati pe ibalopọ ki i ṣe tulaasi, debi ti yoo mu iku wa.
Kóòtù mí-ìn yí ìdájọ̀ padà ní 2025
Lọjọ Aje to kọja yii ni Adajọ Narendra Kumar Vyas, ti ile ẹjọ giga to wa ni Aarin-Gbungbun India, ni Chhattisgarh, yi idajọ 2019 pada, to si ni ki ọkọ iyawo naa maa lọ sile rẹ layọ ati alaafia.
Adajọ Vyas sọ pe ọrọ ti Oloogbe sọ ko too ku nipa ibalopọ ipa naa ko ṣee tẹle.
O ni awọn ẹlẹrii to n sọ pe bẹẹ lo wi tẹlẹ ti ni ki i ṣe ohun to sọ niyẹn.
Ati paapaa, Adajọ Vyas sọ pe ki ọkọ fi ipa ba iyawo rẹ lo pọ lorilẹede India ki i ṣe iwa ọdaran.
O ni ofin ti faaye gba ọkọ lati ba iyawo rẹ ṣere nigba to ba wu u.
Ẹni to ni ẹlẹdẹ ẹgan lo ni abule ni ọrọ ibalopọ fun ọkunrin to ba fẹẹ ba iyawo rẹ sun nigbakugba n'India.
Àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn bínu sí ìdájọ́ yìí
Awọn ajafẹtọọ ati awọn araalu mi-in paapaa ni wọn ti n fi aidunnu wọn han si idajọ tuntun yii lorilẹede India.
" Ka si laju silẹ ka maa wo ọkunrin yii lai jiya ẹṣẹ to ṣe buru jai. Idajọ yii le yẹ labẹ ofin, ṣugbọn idojutini gbaa lo jẹ bi a ba fi oju iwa ọmọluabi wo o."
Agbejọrọ obinrin to tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan, Sukriti Chauhan,
lo sọ bẹẹ fun BBC.
"Idajọ to tu iru eeyan bayii silẹ, koda ki wọn sọ pe iwa to hu ko lodi sofin, otitọ to wa nibẹ ni pe ifasẹyin ati aiba igba yi, ni iru ofin yii jẹ fun eto idajọ wa.
O ti to gẹẹ o, o si ti doju ẹ bayii. Gbogbo iru nnkan bayii gbọdọ yipada kiakia."
Bẹẹ ni lọọya naa sọ.
Lọọya mi-in lati Chhattisgarh, ẹni ti orukọ rẹ n jẹ Priyanka Shukla, sọ pe, "Iru idajọ yii fi han pe ti eeyan ba ti jẹ ọkọ ninu ile, gbogbo ohun to ba n ṣe lo daa
'' Iwọ ni alaṣẹ, o si le ṣe ohun to ba wu ọ, koda ko jẹ eeyan lo pa, apagbe ni."
O fi kun un pe eyi ki i ṣe igba akọkọ ti kootu yoo ṣe iru idajọ yii, idaamu gidi lo si maa n ko ba awọn eeyan ti ko nifẹẹ si iru idajọ bẹẹ.
Idajọ yii ti mu ọpọ eeyan lawujọ India lati maa pe fun fifagile ofin to ni ibalopọ agidi ki i ṣe ẹṣẹ fun ọkọ iyawo.
Wọn ni idajọ ti ko ni aanu rara ni eyi to ṣẹṣẹ waye yii, wọn ko ro ti iyawo to padanu ẹmi rẹ nitori igbadun ọkọ.
Orilẹede India wa lara awọn orilẹede ọgbọn (30), ti ọkọ ti le fipa ba iyawo rẹ lo pọ lai lu ofin ilu.
Awọn mi-in ni Pakistan, Afghanistan ati Saudi Arabia.
Ọpọ iwe ifisun ni awọn tọrọ naa ko dun mọ ti kọ ranṣẹ lati yi abala ofin 375 ilẹ India yii pada, eyi to ti wa bẹẹ lati ọdun 1860.