You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Dayo Amusa faraya, fèsì lórí fídíò TikTok tí ọkùnrin kan ti sọ pé ó lárùn HIV
Gbajumọ oṣerebinrin Yoruba Nollywood, Dayo Amusa, ti leri lati ba ọkan lara awọn to maa n gbe iroyin jade loju opo TikTok, Olaoluwa Segun Solomon, mu nnkan silẹ, lori iroyin ipo ilera oṣere naa to gbe jade.
Fidio kan ti Segun Solomon tawọn eeyan tun mọ si Unofficial_Olas gbe jade nipa Dayo Amusa lo ti kede pe osere naa ni arun HIV lara.
Ninu fidio to fi soju opo TikTok naa lo tun ti darukọ awọn ọmọ Naijiria mẹrin mi-in to ni wọn ti kede pe arun HIV wa lara awọn.
Hanks Anuku, Yinka Jegede Ekpe, Chika wonder ati Fela Anikulapo Kuti ni oniroyin ayelujara naa tun ka mọ awọn to ni arun HIV .
Nigba to n ṣalaye nipa oṣerebinrin Dayo Amusa, Olas sọ pe funra Dayo lo jade to si kede pe oun n gbele aye pẹlu kokoro HIV lara.
O ni oṣere naa tun ṣalaye bi arun yii ṣe ṣakoba fun iṣẹ tiata to n ṣe.
Dayo Amusa ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí
Nigba to n fesi si fidio naa, Dayo Amusa ninu fidio to ṣe tako iroyin TikTok yii, sọ pe loootọ loun kede ipo ilera oun nipa HIV.
O ni bẹẹ loun maa n ṣe laaarin ọdun sira wọn lati la awọn eeyan loye.
Oṣerebinrin naa sọ pe oun n kede ipo ilera naa kawọn eeyan le lọọ ṣayẹwo tiwọn naa, ki ọkan wọn le balẹ bi wọn ko ba ni, ki wọn si le mu ọna itọju pọn to ba ṣẹlẹ.
''Ṣugbọn bi mo ṣe n ṣayẹwo ara mi to ti mo si n kede ẹ, mi o figba kan sọ ọ ri pe mo ni kokoro HIV.
''Ni 2019 ni mo gbe ọrọ kan jade nipa ipo ilera mi lori HIV, ohun ti mo dẹ ṣe gbe e jade ni pe mo ṣe ayẹwo, o si han pe mi o ni kokoro HIV.
'''Mo pinnu lati gbe e jade, ki n si rọ awọn eeyan mi-in lati lọọ ṣayẹwo tiwọn pẹlu, nitori o ṣe pataki lati mọ ọn, ki eeyan si gba itọju to ba jẹ o ti ni.
''Ṣugbọn iyalẹnu nla lo jẹ pe ẹnikan yoo kan waa ka mi mọ awọn eeyan mi-in pe a ni HIV, lai ṣe iwadii to yẹ, o si pin in kari gbogbo ẹka ayelujara''
Dayo sọ pe oun ko mọ bi awọn oniroyin bi eyi ṣe n ṣe tiwọn lati fi ba ti ẹlomiran jẹ.
O ni boya ni wọn tiẹ n ro ipa buruku ti iṣẹ wọn n ni lara awọn eeyan ti wọn n ba lorukọ jẹ.
Ìgbésẹ̀ tó kàn
Gẹgẹ bi Dayo Amusa ṣe wi, o ni oun yoo fi ọmọkunrin to gbe iroyin ofege naa jade jofin.
'' Mo maa ri i daju pe mo fi eleyii jofin, ki i ṣe pe o dun mọ mi lati ṣe bẹẹ, ṣugbọn ko le ba jẹ ẹkọ fun ọ ati awọn yoku tẹ ẹ jọ n gbe iru ẹ jade ni.''
O ni oniroyin yii yoo ni lati ṣalaye ibi to ti ri esi ayewo HIV oun, to fi han pe kokoro naa wa lara oun.
Lakootan, Dayo Amusa loun ko ni HIV, aimọkan lo n ṣe awọn to gbe iroyin naa jade lai ṣe iwadii kikun.
Oniroyin TikTok tọrọ aforiji
Ninu atẹjade kan to fi bẹbẹ, Segun Solomon tọrọ aforiji lọwọ Dayo Amusa.
O ni oun gba pe aṣiṣe loun ṣe lori iroyin yii, ati pe Dayo Amusa ko ni kokoro HIV.
Oniroyin TikTok naa fi kun un pe ẹnikan toun ṣẹṣẹ gba siṣẹ, pẹlu ohun to fa aṣiṣe naa.
O ṣeleri lati maa ṣewadii kikun ko too maa gbe iroyin jade lori ayelujara.
Ṣugbọn bi Dayo Amusa ba mu ileri rẹ ṣẹ bo ṣe wi, aa jẹ pe ọrọ naa yoo lẹyin bi oku Iya Jọjọ.