You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lẹ́yìn tí wọ́n tú ìyá ẹni àádọ́rùn-ún àti èèyàn mẹ́ta mìíràn sílẹ̀, àwọn agbébọn fẹ́ fẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kù ní àhámọ́
Awọn agbebon ti tu iya ẹni ọdun aadọruun, ọmọbirin rẹ pẹlu awọn mẹta miiran silẹ ninu awọn arinrin-ajo reluwee Abuja sí Kaduna ti won jigbe loṣu diẹ sẹyìn silẹ, ti wọn si tun ransẹ pe awọn nifẹ lati fẹ ọmọbinrin kan, ẹni ọdun mọkanlelogun.
Ọkan lara awọn to n junadura pẹlu awọn ajinigbe naa, Malam Tukur lo kede ọrọ naa fun awọn akọroyin niluu Abuja.
Mamu ni iya adọruun ọdun, Halimatu Atta , ọmọ rẹ ẹni ọdun mẹtalelaadọta, Adama Atta pẹlu eeyan meji miiran ti ri itusilẹ.
O ni arabinrin naa ti orukọ rẹ jẹ Azurfa Lios John, ẹni ọdun mọkanlelogun ni ọkan lara awọn ọga agba fun awọn ajinigbe sọ pe oun nifẹ lati fẹ gẹgẹ bi aya.
O ni ti ijọba ko sọra, iru iṣelẹ to ṣelẹ si Leah Sharibu tun ti fẹ waye
“Nkan ti mo gbo lọjọ Ẹti ana nipe awọn ajinigbe ti tu eeyan mẹrin miiran silẹ.
“Sugbọn awọn ajinigbe naa ti ransẹ pe ọkan lara awọn eeyan to wa ni ahamọ, to kere ju,ti bẹrẹ si ni wu ọkan lara ọga agba fun awọn ajinigbe lati fẹ gẹgẹ bi aya.”
Mamu wa rọ ijọba apapọ lati jaramọ bi itusilẹ awọn yooku to wa ni ahamọ yoo ṣe waye
Ninu awọn eeyan mẹtalelọgọta ti awọn ajinigbe naa jigbe, o ku eeyan m mẹtalelogun to si wa ni ahamọ wọn.