Wo ìlú yìí tó ń fojú winá ìkọlù tó ń wáyé ní India àti Myanmar

Awọn ara ilu agbegbe Kuki ni Manipur ti gbe ẹṣọ alaabo dide lati da abo bo ara wọn lọwọ ikọlu ojoojumọ.
Ilu naa lo ba ni ibode orilẹede India ati Mayanmar ti awọn akọnilẹru lati Ilẹ Gẹẹsi ya fun wọn ni ọdun 1948.
Lẹyin ọdun meji ti ijọba ologun gbajọba ni Myanmar ni awọn ikọ ẹṣọ alaabo ti n doju ija kọ awọn ologun ti eleyii si ti fa ogun nibẹ.
Awọn eniyan to le ni 80,000 ni wọn ti sa asala fun ẹmi wọn, ti ọpọ eniyan si n sa lọ si ilu Manipur.
Bio tilẹ jẹpe wọn ni ajọṣọ laarin awọn eniyan ati ijọba mejeeji to gba awọn eniyan laaye lati maa rin kọja, ọdun 2022 ni ijọba India fi ofin de.
Akọroyin BBC se abẹwo si ọgba ẹwọn naa to si salaye ohun to ri lasiko abẹwo rẹ.
O ni awọn ara ilu Myanmar wa ni ọgba ẹwọn ni Manipur, bio tilẹ jẹpe wọn ti lo asiko wọn tan ni ọgba ẹwọn , wọn ko lee lọ si ile.

Iriri awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn.
Akọroyin naa ni oun pade arakunrin Lin Khin Meng to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ni agbegbe Myanmar to si ni oun wa si orilẹede India ki oun le ri aje jẹun.
‘’Mo ma n wa si India lati wa ta malu ni agbegbe Sagaing ni Myanmar. Osu mẹsan ṣẹyin ni wọn fi panpẹ mu mi, ti mo si ti wa ni atimọle lati igba naa.
Iya mi, iyawo mi ati awọn ọmọ mi ko si mọ wi pe mo wa ni atimọle ọhun.
Yul Ning ti o jẹ ẹnikeji ti wọn ti mọle ni ọrọ rẹ di alatimole nitori aigbọraẹniye. O ni ọrẹ oun lo n ta oogun oloro, ti wọn si titori rẹ mu oun, amọ oun ko le pada sile bayii nitori wọn ti ti ibode ilu ọhun.
Awọn wọnyii ni wọn wa ni Manipur ti wọn ko si le lọ sile, ti ijọba tun n da ebi ru wọn pe awọn ni wọn n da ija silẹ nibẹ.

Ija laarin orilẹede meji

Ọpọlọpọ awọn ara ẹya Meiteis ni wọn darapọ mọ rogbodiyan naa laarin awọn onijagidijagan Kuki, ti wọn fi ẹsun kan pe wọn n ta ọja oogun oloro ni agbegbe naa.
Ninu ọrọ rẹ, minisita fun agbegbe naa, N Biren Singh ni ohun gbogbo ko lọ deede pẹlu ibode naa.
‘’Awọn iwa ipa to n waye nibẹ, a ko lee ṣe alaaye, ti awọn ọmọ ogun si wa nibẹ ti wọn n sọ ibẹ lọsan ati ni oru.
Amọ awọn ara agbegbe Kuki ni wọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ti wọn si da ẹbi ru awọn to ko wa ni agbegbe naa nitori wọn la ala lai kọ ibi ara si ede ati aṣa awọn eniyan nibẹ.
Bakan naa ni wọn ni pe awọn ẹni ibi kan yọ wọ aarin wọn ti wọn si n hu iwa ibajẹ ni agbegbe naa.
Ọkan lara awọn mọlẹbi to ti n gbe agbe naa fun ọpọlọpọ ọdun, Davvid Vaiphei ni oun gbiyanju lati da abo bo agbegbe naa ati lati jẹ ki awọn eniyan mọ pe ko si otitọ ninu ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Igbesẹ ijọba lati da abo bo ilu ọhun

Ijọba orilẹede India ti sọrọ lori ati da abo bo agbegbe naa ti wọn si fẹ mọ ogiri yi agbegbe naa ka.
Bakan naa ni wọn ni awọn ti fi panpẹ mu awọn arinrinajo to le ni 2,500 ti wọn wa nibẹ lọna aitọ.
Bakan naa ni Minisita fun ọrọ abẹle ni India, Amit Shah ni ọrọ ibode naa wa niwaju awọn aṣofin lorilẹede naa.
O ni ijọba ti ko ẹgbẹgbẹrun awọn ẹṣọ alaabo sita lati da aabo bo awọn araalu lọna ati pana ogun nibẹ.
Igbakeji aarẹ agbegbe Kuki ni ẹgbẹ oṣelu Kuki People’s alliance, Chinholal Thangzing wa kesi awọn eniyan lati gba awọn alajo laaye lai dẹyẹ si wọn, ki wọn si gbe ni alaafia












