Èèmọ̀ ń bọ̀ l‘Osun! Àṣírí tú pé agbébọn fẹ́ máa jí akẹ́kọ̀ọ́ àti àgbẹ̀ gbé lọ - Adeleke pariwo

Onbọ, onbọ, awọn la a dẹ de e, amọ lode oni, oju ni wọn n mu to.

Idi ree ti gomina Ademola Adeleke se kesi gbogbo ileesẹ ẹṣọ alaabo to wa ni ipinlẹ Osun, lati se afikun ipese aabo fun ẹmi ati dukia fawọn ara ilu nibi ipade apero kan.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ́ Osun, Rasheed Olawale fi sita ni ipade apero naa lo waye ni ọfiisi Gomina.

Nibi ipade naa ni Gomina Adeleke ti ba awọ̀n ọga ẹṣọ alaabo kọọkan sọrọ lori asiri ọrọ kan ti wọn gbọ lọ́dọ̀ awọ̀n ọ̀tẹ́lẹ̀múyẹ́.

Asiri naa lo ni awọn janduku ajinigbe fẹ ṣe ikọlu si awọn ile ẹkọ atawọn igberiko kan pẹlu erongba lati awọn akẹ́kọ̀ọ́ ati agbẹ.

"Mo ṣetan lati ro Amotekun lagbara ko le pese eto aabo to tọ fawọn araalu"

Gomina Adeleke ni oun gbọ pe, awọn to fẹ se ikọlu si igberiko naa fẹ ṣe bẹẹ nipasẹ jiji awọn agbẹ to wa ni igberiko gbe lọ.

Gomina ni bẹẹ si ni awọn janduku naa fẹ tun ṣe ikọlu si àwọn ile ẹkọ to wa ni igberiko kaakiri ipinlẹ Osun.

Gomina Ademola Adeleke wa fi ọwọ́ gbaya pe oun ti ṣetan lati ro awọn ẹṣọ aabo Amotekun lagbara lati le ṣe iṣẹ wọn bo se yẹ, nipa pipese eto aabo to tọ fawọn araalu.

O ni oun fẹ mu agbega ba Amotekun, ki wọn le maa ṣe iranlọwọ fun awọn ọlọpaa ati ẹṣọ aabo yooku.

Ẹ fi ṣọ́rí bíi alakan, ẹ̀yin araalu, ẹ maa kiyesi ohun ajoji to n ba waye ni agbegbe koowa yin"

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Kọmiṣanna fun eto iroyin ipinlẹ Osun, Kolapo Alimi ni gomina Adeleke ko fi ìgbà kankan tura silẹ nipa eto aabo rara.

Kolapo ni bi Gomina Adeleke ti gbọ iroyin naa lo ti yara pe ipade pajawiri pẹlu awọn ti ileesẹ́ aabo ọrọ kan lai tete wa ojutuu si ọrọ naa.

Kọmiṣanna naa wa rọ gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Osun lati fọkan balẹ pe gomina ti n ṣe ipade pẹlu awọn to yẹ.

O ni ati pe o ti beere fun ifọwọsowọpọ gbogbo awọn ẹṣọ aabo to wa ni Ìpínlẹ̀ Osun lati ri wi pe ko si wahala tabi ikọlu kankan fun gbogbo olugbe ipinlẹ ọhun.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe, gomina ti beere lọwọ ọga ẹṣọ aabo kọọkan lati le mọ ọna to le fi kun wọn lọwọ lati rí daju pe aabo wa fun ẹmi ati dukia awọn olugbe Ìpínlẹ̀ Osun.

Bakan naa lo rọ awọn ipinlẹ̀ Osun lati fi ṣọ́rí bíi alakan, ki wọ́n si maa kiyesi ohun ajoji kan to n ba waye ni agbegbe koowa wọn.

Kii se oni ni igbaradi wa ti bẹ̀rẹ̀ – Agbẹnusọ ọlọpaa Osun, lákọ la wa, bii ibọn"

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola ni iku to n pa ojugba ẹni n pa owe fun ni ni ọrọ eto aabo Naijiria jẹ lọwọ ti a wa yii.

O ni ko ṣẹṣẹ digba ti awọn ba to kẹfin iru iroyin afunilara bayii, ki awọn to gbaradi.

Opalola ni tipẹtipẹ ni awọn ti wa lakọ bi ibọn nitori eto aabo kii ṣe ohun ti eeyan maa n fi ọwọ yẹpẹrẹ mu rara.

O ṣalaye pe gbogbo igba ni awọn ọlọpaa ipinlẹ Osun maa n ṣe ipade pẹlu awọn ẹsọ aabo to ku lati ri daju pe ibaṣepọ to danmọran wa laarin awọn..

O ni loootọ ni awọn naa gbọ iroyin pe awọn kan n gbero lati ṣe ikọlu si ipinlẹ Osun ti awọn si ti gbaradi lati koju oniruuru ikọlu to ba n bọ.

Opalola tun sọ pe Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Osun, Mohammed Umar Abba ti pe gbogbo awọn alabaṣiṣẹpọ ẹsọ aabo to ku lati gbaradi fun iroyin to de etigbọ wọn.

O wa gba gbogbo olugbe ipinlẹ Osun nimọran lati ma rin irinajo ni owurọ kutukutu tabi rin irinajo alẹ. Kí wọn fi ọkan balẹ ki wọn si maa fi ohun to ba ru wọn loju nipa eto abo to Ọlọpaa leti ni kiakia.