Wo obìnrin aláàbò ara ẹni ọdún 43 tó bẹ aṣẹ́wó ọkùnrin lọ́wẹ̀ láti já ìbálé rẹ̀

Obinrin alaabo ara kan, Meet Melanie, ti bẹ ọkunrin aṣẹwo kan lọwe lati ja ibale rẹ.

Asiko ti Melanie wa ni igbele ajakalẹ arun Corona lo pinnu lati ni ibalopọ fun igba akọkọ.

Orukọ ọkunrin aṣẹwo naa ni Chayse.

Ṣaaju asiko ti wọn ja ibale rẹ ọhun, ọkunrin kankan to kii fi ọwọ kan Melanie to jẹ ẹni ọdun mẹtalelogoji ri, ayafi awon dokita to ṣetọju rẹ gẹgẹ bii alaabo ara.

Gẹgẹ bi ohun to sọ, olutọju rẹ kan, Tracey, lo fun ni imọran lati gbe iṣẹ ibalopọ naa fun ọkunrin to jẹ aṣẹwo.

O ni “Imọran naa ṣi mi loju pe emi naa le bẹ aṣẹwo lọwọ lati ja ibale mi,” lẹyin naa lọ sori ayelujara, nibi to ti ri ọkunrin kan ti wọn pe ni Chayse, lẹyin ti wọn dunadura tan lo lọ sile Chayse.

“Mo mọ pe mi o ni iriri to pọ rẹpẹtẹ nipa ibalopọ, amọ ara mi o balẹ nigba ti mo ri ọkunrin ọhun.”

“Nigba ti a pade, a sọrọ nipa awọn ohun ti a mọ atawọn eyii ti a ko mọ, lẹyin wakati meji, awa mejeji ti jọjọ n rẹrin bii pe o ti pẹ ti a ti mọ ara wa.”

Melanie tẹsiwaju pe eredi ti oun ṣe bẹ akọṣẹmọṣẹ aṣẹwo ọkunrin lọwe ko ṣeyin pe oun ko fẹ ba ọkunrin ajoji ti oun pade nile ọti ni ibalopọ oun akọkọ, oun si fẹ gbadun ibalopọ naa daadaa bo tilẹ jẹ pe oun jẹ alaabo ara.

O ṣalaye pe “Ọjọ naa jẹ igba akọkọ ti mo maa wa ni ihoho niwaju ọkunrin, ti kii sii ṣe nile iwosan.”

“Ṣugbọn mo mọ pe niwọn igba to jẹ pe owo ni mo san, mo mọ pe ti Chayse ba ṣe nnkan ti mi o fẹ mo lẹtọọ lati sọ pe mi o ṣe mọ.”

Lẹyinorẹyin, ibalopọ naa waye laarin Melanie ati Chayse, awọn mejeji si ti di ọrẹ bayii, koda Chayse ti n ba Melanie wa ololufẹ.

Melanie sọ pe “Mo ti n wa ẹlomiran ti yoo rọpo Chayse bayii... ẹni ti yoo nifẹ mi atawọn ohun ti mo fẹran, ti ko si ni gba owo ibalopọ lọwọ mi.”