You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ̀sùn wo ni wọ́n fi kan Iyiola Omisore tí ipò akọ̀wé APC fi bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀?
Iroyin to gba igboro kan ni ana ọjọ Aje ni pe akọwe apapọ gbogbo gboo fun ẹgbẹ oselu to n se ijọba lọwọ, APC. Sẹnatọ Iyiola Omisore, ti kọwe fipo rẹ silẹ.
Idi ọrọ yii si lo fidi mulẹ nigba ti Sẹnetọ Abubakar Kyari di adele alaga gbogbogbo fun ẹgbẹ oṣelu naa, eyi ti wọn kede lanaa bakan naa.
Nígbà ti Kyari n ba awọn akọroyin sọ̀rọ̀ lẹyin ipade igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ APC to waye, o kede pe ni ibamu pẹlu ofin ẹgbẹ́, igbakeji akọ̀wé agba ẹgbẹ́, Festus Fuanter ni yoo maa ṣiṣẹ́ gẹgẹ bi akọ̀wé agba bayii dipo Iyiola Omisore.
Lori idi ti Omisore fi kọwọrin pẹlu Adamu lati kọwe fipo silẹ, Kyari ni, "ni ikorita yii, awọn ẹni to kọwe fipo silẹ ṣe e lọwọ ara wọn ni.
Oun ti a si le sọ lọwọlọwọ yii ree. Idi ti wọn fi kọwe fipo silẹ yoo maa to yin leti lọjọ iwájú."
Igbakeji alaga ẹgbẹ́ APC níhà Ariwa naka aleebu si Omisore pe o se owo idibo nipinlẹ Osun basubasu
Adamu ko yọjú síbi ipade ọhun amọ ni ti Omisore, iroyin ni ṣe lo dede binu kuro ni ọfiisi ẹgbẹ́ òṣèlú naa ni Abuja nigba ti wọn ni ko raye wọle sinu ile ẹgbẹ naa.
Bakan naa, lori eto Ileeṣẹ amohunmaworan Channels to waye ni ọjọ díẹ̀ sẹ́yìn, Omisore na ika aleebu si igbakeji alaga ẹgbẹ́ níhà Ariwa, Salihu Lukman gẹgẹ bii "ẹni to n da agbo ẹgbẹ oselu naa ru".
Ẹwẹ, Salihu Lukman, ti Omisore ń ba wi yii, naa ti fi ẹsun lilo owo ẹgbẹ́ to yẹ ko wa fun ipolongo ibo báṣubáṣu kan Omisore.
Salihu sọ pe ni Ìpínlẹ̀ Osun, Omisore ko se ibo idibo daadaa bo se yẹ, to si tun tahun pada pe ati Adamu ati Omisore n wa ọna ati sọ ara wọn di Alayeluwa ninu ẹgbẹ́ APC ni.
Ohun tí a mọ̀ nípa bóyá Iyiola Omisore kọ̀wé fipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọ́wé ẹgbẹ́ APC rèé
Iroyin ti gba igboro kan wipe Alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress(APC) ni ẹkun Ariwa, Sẹnetọ Abubakar Kyari ti di alaga gbogbogbo fun ẹgbẹ oṣelu naa.
Eyi waye lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu naa pari ipade wọn nilu Abuja lọjọ Aje.
Kyari funrarẹ lo kede eyi fun awọn oniroyin wipe alaga ẹgbẹ́ òṣèlú naa, Sẹnetọ Abdullahi Adamu ti kọwe fi ipo silẹ lẹyin ọdun kan ati oṣù meji to ti n dari ẹgbẹ́.
Ní bayii, adele alaga ẹgbẹ́ ni Sẹnetọ Abubakar Kyari to si fi aridaju han pe lóòótọ́ ni Adamu ti fi ipo rẹ silẹ lẹyin ọjọ kan ti awọn Ileeṣẹ iroyin Naijiria gbe e wipe aawọ bẹ silẹ laarin adari ẹgbẹ́ òṣèlú APC ati ijọba Ààrẹ Bola Tinubu eyi lo si mu ko kọwe fipo silẹ.
Bakan naa, igbimọ Aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú fọwọ́ sii ninu ipade wọn lọjọ Aje pe ki Abubakar Kyari to jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ́ ni iha Ariwa di ipo alaga igbimọ májẹ̀óbàjẹ̀ mu.
Ẹwẹ, Iroyin sọ pe alaga tẹ́lẹ̀ naa, Adamu ati akọwe agba ẹgbẹ́ yii, Sẹnetọ Iyiola Omisore ni wọn jọ kọwe fi ipo silẹ.
Oṣù díẹ̀ ṣáájú idibo Ààrẹ to waye ninu oṣù keji ọdun yii ni Adamu di adari ẹgbẹ́ náà.
Àmọ́ ṣá, ìjà laarin awọn adari ẹgbẹ́ ti n waye lati akoko ti Ààrẹ Bola Tinubu ti gori aleefa ni nnkan bi oṣù meji sẹ́yìn.
Bi iroyin ìkọ̀wé fipo silẹ alaga ẹgbẹ́ ṣe wa dede bu jade yii n ṣafihan pe ogiri ẹgbẹ́ wọn ti la ti alangba si ti ribi wọlé amọ ọpọ lo n sọ pe eyi lee ko ipa nla lori yiyan awọn ti yoo ba Ààrẹ ṣiṣẹ́ to fi mọ ohun to yẹ ki ijọba gbajumọ.
Ki lo da ija silẹ?
Ko tii ye ohun to fa ija laarin ẹgbẹ́ ati ohun to wa ṣokunfa ìkọ̀wé fipo silẹ alaga.
Ẹwẹ, lasiko ti igbaradi fun idibo abẹle fun ipo Ààrẹ lẹgbẹ òṣèlú APC n waye ninu oṣù kẹfà ọdun 2022, alaga naa, ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin doju kọ wahala lẹyin ti iroyin ni pe o ṣe atilẹyin Ààrẹ ile igbimọ aṣofin nigba naa gẹgẹ bi oludije to yẹ ki ẹgbẹ́ yan fun ipo Ààrẹ.
Igun ẹgbẹ́ awọn gomina kan láti ìhà Ariwa kọ ẹyin si igbeṣe rẹ yii ti wọn si ni Bola Tinubu ni awọn fẹ. Tinubu ọhun lo pada bori lábẹ́lé to si tun jawe olubori gẹgẹ bi Ààrẹ.
Lẹyin ti wọn pari ipade pajawiri kan laarin ẹgbẹ́ lọjọ Aje, Abubakar Kyari sọ fawọn oniroyin pe ko si eredi kankan to wa ninu lẹta ifipo silẹ ti alaga naa kọ.
Lọwọlọwọ, ẹgbẹ́ òṣèlú APC ati Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu n koju ipenija to lọwọ ofin ninu latari abajade eto idibo Ààrẹ to waye ni ọjọ kẹ́ẹdọgbọn oṣù keji.
Awọn alatako rẹ gbòógì meji, Atiku Abubakar ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ati Peter Obi ti ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party n pe fun ki ile ẹjọ́ to n gbọ́ ẹjọ́ nípa eto idibo wọgile idibo naa latari ẹsun magomago tí wọ́n fi kàn.