You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn ọ̀nà láti dènà àìsàn ibà Lassa, èèyàn mẹ́tàlá ló tún lùgbàdì rẹ̀ ní Ondo
Àjọ tó ń rí sí àjàkálẹ̀ ààrùn ní Nàìjíríà ìyẹn Nigeria Centre for Disease Control and Prevention, NCDC ti kéde pé èèyàn mẹ́tàlá ló tún ti lùgbàdì àìsàn ibà ọ̀rẹ̀rẹ̀ lassa.
NCDC nínú àtẹ̀jáde kan tó wà lójú òpó ìtàkùn ayélujára sọ pé ìjábọ̀ náà ló wà fún ọ̀sẹ̀ ogójì èyí tó jẹ́ ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹsàn-án sí ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹwàá, ọdún 2025.
Àjọ náà sọ pé ní ìpínlẹ̀ Ondo àti Edo ni wọ́n ti ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ tuntun náà.
Àkọ́ọ́lẹ̀ tuntun yìí, gẹ́gẹ́ bí NCDC ṣe sọ, fi hàn pé èèyàn 924 ló ti ní àìsàn iba lassa ní ọdún 2025 nìkan, táwọn èèyàn 172 sì ti pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àìsàn ọ̀hún ní ìjọba ìbílẹ̀ 106 ní ìpínlẹ̀ mọ́kànlélógún.
Èyí fi hàn pé ìdá méjìdínlógún èèyàn nínú àwọn tó kó àìsàn náà ló ti ba lọ lọ́dún 2025, àlékún sí iye èèyàn tó bá àìsàn náà lọ́dún 2024.
Gẹ́gẹ́ bí àkọ́ọ́lẹ̀ náà ṣe sọ èèyàn 117 ni wọ́n fura sí pé ó le lùgbàdì àìsàn náà ní ọ̀sẹ̀ ọ̀hún kí wọ́n tó fìdí èèyàn mẹ́tàlá múlẹ̀.
NCDC ṣàlàyé pé ìdá àádọ́rùn-ún gbogbo àwọn àìsàn tí wọ́n ṣàkọ́lẹ̀ rẹ̀ ló jẹ́ láti ìpínlẹ̀ Ondo, Edo, Bauchi, Taraba àti Ebonyi, tí wọ́n jẹ́ ìpínlẹ̀ ti àìsàn náà ti gbilẹ̀ jùlọ.
Wọ́n sọ pé àwọn ní ìfarajìn sí ṣíṣe àmójútó àìsàn lassa, ṣe àtúnṣe àwọn ilé àyẹ̀wò káàkiri Nàìjíríà láti dènà àtànkálẹ̀ àìsàn náà.
Bákan náà ni wọ́n rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti máa ri pé àyíká wọn wà ní tónítóní, kí wọ́n sì dènà jíjẹ nǹkan tí eku bá ti tẹnubọ̀.
Wọ́n tún pàrọwà sáwọn èèyàn tí wọ́n ń ní àmì àpẹẹrẹ bíi ọ̀nà ọ̀fun dúndùn, àyà dídùn láti tètè kàn sí ilé ìwòsàn ní kíákíá.
Ẹ ó rántí pé ní oṣù Kẹta ọdún 2025 ni dókítà kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ondo sọ́wọ́ àìsàn ibà Lassa.
Dókítà náà, ẹni tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n jáde láyé nígbà tó wá sí Nàìjíríà láti UK.
Ọ̀gá àgbà fún àjọ NCDC, Dókítà Jide Idris ṣàlàyé pé àwọn ààmì tó jẹyọ lára olóògbé náà nígbà tó wà nílé ìwòsàn kan jọ ti àìsàn ibà Lassa ló jẹ́ kí wọ́n lọ ṣe àyẹ̀wò rẹ̀.
Ọjọ́ Kìíní, oṣù Kẹta, ọdún 2025 ni dókítà náà jáde láyé kí àyẹ̀wò ìlera tí wọ́n ṣe fún tó jáde lọ́jọ́ Kẹrin, oṣù Kẹta, ọdún 2025.
Àwọn ọ̀nà láti dènà àìsàn ibà Lassa
Àìsàn ibà ọ̀rẹ̀rẹ̀ Lassa jẹ́ àìsàn tí kò ní ẹ̀rọ̀ àmọ́ tó ní ìtọ́jú ti èèyàn tó bá nib á tètè lọ sí ilé ìwòsàn láti fi ara rẹ̀ hàn.
Àìsàn ibà Lassa jẹ́ èyí tí eku tàbí ẹran ìgbẹ́ máa ń fà.
Ọ̀nà láti dènà àìsàn Lassa tí ó wà láti ara ẹran ìgbẹ́ pàápàá eku inú ilé ni:
- Ṣíṣọ́ra fún jíjẹ eku tàbí ẹran ìgbẹ́
- Dídénà sísá gààrí síta tí eku le tẹnubọ̀
- Ẹ rí dájú pé ẹ̀ ń pa àwọn eku tó wà ní agbègbè yín
- Ẹ gé gbogbo koríko àti àwọn igbó tó bà wà ní àyíká yín
- Ẹ ṣọ́ra fún fífi ara kan ẹni tó bá ní àìsàn ibà tí kò tètè lọ