Àwọn èrò fò bọ́ sílẹ̀ láti ojú fèrèsé níbi ìjàmbá ọkọ̀ ojú irin tó gbẹ̀mí èèyàn 15

    • Author, Sahnun Ahmed
    • Author, Abdishukri Haybe
    • Role, BBC Somali
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ìjàmbá ọkọ̀ ojú irin kan ti ṣokùnfà ikú èèyàn mẹ́ẹ̀dógún ní ìlàoòrùn orílẹ̀ èdè Ethiopia gẹ́gẹ́ bí àwọn aláṣẹ orílẹ̀ èdè náà ṣe sọ fún BBC.

Níṣe ni àwọn èrò ń sáré fò bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ náà lẹ́yìn tó yà bàrà kúrò ní ojú ọ̀nà rẹ̀ ní agbègbè Shinile kó tó forí sọ ọkọ̀ ojú irin míì.

Iye èèyàn tó farapa níbi ìjàmbá kò ì tíì yé ṣùgbọ́n àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé ń sọ pé àwọn èèyàn tó farapa wà láàárín mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n sí mọ́kàndínlọ́gbọ̀n.

Àwọn àwòrán tí àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé fi sórí ayélujára ṣàfihàn bí ará ọkọ̀ ojú irin náà ṣe dojúdé.

"Ohun tó ṣokùnfà ìjàmbá ọkọ̀ ojú irin náà ni pé ọkọ̀ ojú irin ọ̀hún kò dára tó bẹ́ẹ̀ mọ́ nítorí pé ó ti gbó, tí kò sì le gba ẹ̀rù tó wúwo. A gbàgbọ́ pé ohun tó ṣokùnfà ìjàmbá ni àpọ̀jù ẹrù àti èrò," Kọmíṣánnà fún ẹkùn náà, Jibril Omar sọ fún BBC News Somali.

Ó sọ pé ọkọ̀ ojú irin náà kó àwọn èrò àti ẹrù bíi ìrẹsì àti òróró.

"Lára àwọn èrò tó wà nínú ọkọ̀ náà ni àwọn ọ̀dọ́ tó sì jẹ́ pé wọ́n sáré fò bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ náà," Omar sọ.

Ó fi kun pé ọkọ̀ ojú irin náà ló ń ṣe ìrìnàjò láàárín Dewele àti Dire Dawa kó tó di pé ìjàmbá ọ̀hún wáyé.

Agbẹnusọ fún ìjọba ẹkùn Somali, Mohammed Adem sọ pé gbogbo àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn àti tó farapa ni wọ́n ti kó kúrò níbi ààyè tí ìjàmbá náà ti wáyé.

Ó fi kun pé ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ohun tó ṣokùnfà ìjàmbá náà.

Ìjàmbá ọkọ̀ ojú irin kìí sábà wáyé ní orílẹ̀ èdè Ethiopia tó jẹ́ orílẹ̀ èdè tí èrò pọ̀ sí jùlọ ní Africa.

Ẹkùn Somali ni ó tóbi jùlọ ní Ethiopia, tó sì jẹ́ pé àwọn ẹ̀yà Somali ló ń gbé níbẹ̀ júlọ.

Àfikún ìròyìn láti ọwọ́, Amensisa Ifa, BBC Africa